Wọn ti mu Abba Kyari, ọga ọlọpaa ti wọn lo n ṣowo ẹgboogi oloro

Faith Adebọla

Ọwọ agbofinro ti ba DCP Abba Kyari, ọga ọtẹlẹmuyẹ ana ti wọn fẹsun kan pe o wa lara awọn kọlọransi to n ṣowo egboogbi oloro lagbaaye.

Ba a ṣe gbọ, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinla, oṣu keji yii, lawọn ẹṣọ ajọ to n gbogun ti lilo, gbigbe ati ṣiṣẹ okoowo egboogi olori nilẹ wa, NDLEA (National Drug Law Enforcement Agency), lọọ fi pampẹ ofin mu ọkunrin naa, lẹyin ti iṣẹ iwadii to lọọrin ti fidi ẹ mulẹ pe ọkunrin naa n ba wọn lọwọ si iwa irufin gbigbe egboogi oloro, lasiko to fi wa nipo olori awọn ọtẹlẹmuyẹ.

Bakan naa la gbọ pe wọn mu awọn mẹrin mi-in pẹlu rẹ, ti iwadii fihan pe wọn jọọ gbimọ-pọ huwa ọdaran naa ni.

Wọn ni iṣẹ iwadii ṣi n tẹ siwaju.

Ajọ NDLEA lo kọkọ ṣe kede laaarọ ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii pe awọn n wa olori awọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa tẹlẹri naa, wọn ni iwadii ti taṣiiri ẹ pe o lọwọ ninu okoowo gbigbe egboogi oloro.

Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, ti i ṣe Agbẹnusọ fun ajọ NDLEA (National Drug Law Enforcement Agency), to n gbogun ti gbigbe, lilo ati ṣiṣe okoowo egboogi oloro nilẹ wa, lo ṣi ọrọ naa paya fawọn oniroyin lọjọ kẹrinla, oṣu keji yii, niluu Abuja pe afurasi ọdaran ni Abba Kyari, o si lẹjọ ijẹ lọdọ awọn.

O ṣalaye pe iṣẹ iwadii to lọọrin kan tawọn ṣe laipẹ yii lo gbe orukọ ọga ọlọpaa naa jade, wọn lo wa lara ẹgbẹ awọn kọlọransi ẹda kan to n ṣowo egboogi oloro kiri agbaye.

Leave a Reply