Wọn ti mu Ahmed to pa alaabagbe rẹ nitori abọ ounjẹ n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Wọn ni ẹgbẹrun saamu kan ko le sa mọ Ọlọrun lọwọ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni wọn fi panpẹ ofin gbe Ahmed Yakubu, akẹkọọ ileewe olukọni agba Kinsey, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, to ṣeku pa alaabagbe rẹ, Farouk Ojo Ahmed, nitori abọ ounjẹ.

Tẹ o ba gbagbe, oṣu to kọja yii ni Ahmed gun Ahmed lọbẹ pa latari edeiyede kekere kan to  bẹ silẹ laarin wọn lori ọrọ ounjẹ, eyi lo mu ki wọn ma dana pọ mọ, ṣugbọn ọrọ abọ ounjẹ ti Farouk ko sọdọ lo di wahala, ti Ahmed fi gun un lọbẹ. Wọn sare gbe Farouk, lọ si ileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin (UITH), Loke-Oyi, Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ibẹ ni o ti mi imi kẹyin.

Ni bayii, wọn ti fi panpẹ ofin gbe Ahmed, wọn si ti wọ ọ lọ si ile-ẹjọ Majistreeti kan to fi ilu Ilọrin ṣebujokoo. Agbefọba Samuel Adebisi, rọ ile-ẹjọ pe ko fi ọmọkunrin afurasi naa si ahamọ titi ti adajọ yoo fi gba imọran lọwọ ileeṣẹ to n risi ẹka eto idajọ nipinlẹ naa.

Onidaajọ Adebayọ Kudus, ti wa sọ pe oun ko lagbara lati da ẹjọ naa, sugbọn oun yoo gba imọran lori rẹ, ṣugbọn ki wọn fi Ahmed sahaamọ titi ti igbẹjọ yoo fi waye.

Leave a Reply