Wọn ti mu Akande o, afurasi ọdaran to ta ọrẹbinrin rẹ fun babalawo lati fi ṣetutu ọla

Adewale Adeoye

Afi bii ẹyẹ awọn agba ni afurasi ọdaran kan, Ọgbẹni Raman Akande, to pa aṣẹwo kan lagbegbe Ifọ, nijọba ibilẹ Ifọ, nipinlẹ Ogun, fun babalawo kan lati fi ṣetutu ọla n ka lọdọ awọn ọlọpaa agbegbe Ifọ bayii.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun naa si ti fidi rẹ mulẹ pe ọdọ awọn ni awọn afurasi ọdaran mẹta ti wọn lẹdi apọ pọ lati pa aṣẹwo kan lagbegbe Ifọ laipe yii wa. Ọgbẹni Raman Akande to tan aṣẹwo naa lọ sile lọwọ awọn agbofinro kọkọ tẹ, lẹyin ti wọn fọwọ ofin mu un tan lo too darukọ awọn ọrẹ rẹ kan to ran an lọwọ, ati babalawo to yọ awọn ẹya ara oloogbe naa lọ lati fi ṣetutu ọla.

ALAROYE gbọ pe babalawo kan tawọn eeyan mọ si Ifa, lo gbeṣẹ fun Akande pe ko b’oun wa eeyan lati fi ṣetutu ọla, ẹgbẹrun lọna ọgọrun marun-un Naira lowo to ṣeleri pe oun maa san fun un. Owo naa lo ran mọ Akande loju to fi gba lati tan aṣẹwo kan toun ati ẹ ti jọọ wa tipẹ, to si pa a danu.

Nigba to n ṣalaye ipa to ko lori ọrọ naa fawọn ọlọpaa, Akande ni, ‘‘Babalawo kan ti wọn n pe ni Ifa, lo sọ fun mi pe oun maa fun mi ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un marun-un Naira, bi mo ba le b’oun wa eeyan lati fi ṣetutu ọla. Mi o lowo lọwọ lasiko naa ni mo ṣe gba lati ba a ṣiṣẹ ọhun. Ọdọ aṣẹwo kan to jẹ ọrẹbinrin mi ni mo gba lọ, mo sọ fun un pe ko waa sun lọdọ mi mọju, pe ma a fun un lẹgbẹrun mẹta Naira gẹgẹ bii owo iṣẹ rẹ. Ẹgbẹrun kan Naira lowo ti mo maa n san fun un tẹlẹ, ṣugbọn nitori pe mo fẹ ko waa sun lọdọ mi lọjọ naa ti ma a fi le ri i pa ni mo ṣe fun un lowo to pọ to bẹẹ yẹn. O gba lati waa sun lọdọ mi, bo ṣe de ọdọ mi ni mo lagi mo ọn lori lati ẹyin, mo wọ ọ wọle, kawọn araale ibi ti mo n gbe ma baa ri i, mo di i lọwọ mu, ọrẹ mi kan naa ba mi di ẹsẹ rẹ mu daadaa, ni Ifa to fẹẹ lo ẹya ara eeyan ba du u lọbẹ lọjọ yii. O gbe ẹjẹ rẹ sinu igba nla kan’’.

Ọwọ awọn ọlọpaa agbegbe Ifọ pada tẹ afurasi ọdaran ọhun lẹyin iwadii ti wọn ṣe nipa iṣẹlẹ ọhun.

Wọn si ti gbe ẹjọ naa lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fun iwadii nipa iṣẹlẹ ọhun.

Leave a Reply