Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti mu baba ọgọta ọdun kan, Bọlaji Ọlarongbe, ati ẹnikeji ẹ, Mọshood Shittu, ẹni ọdun marun-unlelogoji, fẹsun ole jija ati ile fifọ.
Ninu atẹjade kan to tẹ ALAROYE lọwọ, eyi ti Alukoro ajọ naa nipinlẹ ọhun, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, lo ti salaye pe Shittu o maa n lọọ fọle, ti Ọlarongbe si maa n gba ẹru lọwọ rẹ, ṣe agbepo laja o si jale bii ẹni gba a silẹ ni Yoruba wi. O tẹsiwaju pe awọn ẹru ti wọn ri gba lọwọ awọn ogbologboo ole naa ni awọn kọmuta alaagbeletan (laptop), awọn foonu ilewọ ọlọkan-o-jọkan, awọn eroja foonu, DVD ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Afọlabi ni ọjọ Aiku, Sunnde, ọjọ keje, oṣu kọkanla, ọdun yii, ni Arabinrin kan, Yemisi Adefila, ẹni ọdun mejilelogoji, to n gbe ni agbegbe Gaa Akanbi, niluu Ilọrin, mu ẹsun lọ si ọfiisi ajọ naa pe Moshood Shittu fọle awọn obi ọhun, to si ji ọpọ awọn ohun eelo ile bii dikoda GOtv, silinda gaasi, DVD ati bẹẹ bẹẹ lọ gbe sa lọ. Lẹyin ti wọn mu Shittu tan lo jẹwọ pe loootọ loun fọ ile naa, to si mu ajọ NSCDC lọ sile Ọlarongbe to wa ni agbegbe G220, agboole Yekelu, Bọlanta, niluu Ilọrin, ibẹ ni wọn ti ba gbogbo awọn nnkan ti wọn jigbe ọhun.
Adari ajọ ọhun, Ọgbẹni Makinde, ti waa ni ki wọn ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun, ki wọn si foju awọn ọdaran naa ba ile-ẹjọ laipẹ.