Wọn ti mu Dosu to pa Alaaji Jimọh olotẹẹli n’Idiroko

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Lasiko ti Korona n gbona lọwọ lorilẹ-ede yii, ninu oṣu karun-un, ọdun yii, ni awọn olugbe agbegbe Ọmọ Ilu-Owotẹdo, n’Idiroko, deede ri oku ọkunrin olotẹẹli kan ti wọn n pe ni Alaaji Jimọh Bello. Ẹyin ọkọ ni wọn ju oku ẹ si, ko sẹni to mọ bo ṣe debẹ.

Afi l’Ọjọbọ ọsẹ yii tawọn ọlọpaa foju ọmọ ogun ọdun pere kan han, ọmọ ti wọn pe orukọ ẹ ni Misipode Dosu naa lo fun Bello ni majele jẹ gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe wi.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi ṣalaye ninu atẹjade to fi sita, pe ọmọdekunrin to n jẹ Dosu yii n ṣiṣẹ babalawo ni.

O ni nigba tọwọ ba a lẹyin iwadii tawọn ṣe lo jẹwọ pe Alaaji Jimọh Bello to ni Otẹẹli J.B, l’Owode-Yewa, bẹ oun loogun owo lati ṣe ni.

Dosu loun ni ki ọkunrin naa san ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira (300,000), o si ti foun ni ẹgbẹrun lọna igba ataabọ (250,000) ninu ẹ, ṣugbọn nigba ti iṣẹ to bẹ oun naa ko dahun lo bẹrẹ si i binu, to n halẹ mọ oun.

Ko si ma di pe yoo lọọ sọrọ naa fọlọpaa, o ni nitori ẹ loun ṣe pe e lalẹ ọjọ toun pa a naa pe ko waa ṣe etutu ikẹyin ti yoo maa mu owo wọle fun un.

Eyi lo mu Alaaji Bello dagbere funyawo ẹ, n lo ba kuro nile pẹlu mọto Camry ẹ, o di ọdọ Dosu. Afi bo ṣe jẹ pe alọ rẹ ni wọn ri, ti wọn ko ri abọ.

Asejẹ iku, ewe ti majele wa ninu ẹ lọmọkunrin kekere yii gbe fun baba to too bi i lọmọ naa, to ni ko o jẹ ẹ. Nigba tiyẹn ko si mọ pe majele loun fẹẹ jẹ, o jẹ asejẹ naa, ẹsẹkẹsẹ lo ṣubu lulẹ, to si dagbere faye.

Bi eyi ṣe ṣẹlẹ ni babalawo kekere yii gbe oku Alaaji Jimọh sẹyin ọkọ ẹ, o si wa a lọ sagbegbe Ọmọ-Ilu Owotẹdo, o ba tiẹ lọ.

Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2020 yii, ni wọn ri oku Alaaji Jimọh to ti wu lẹyin ọkọ naa;  latigba naa lawọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii, ko too ye wọn pe Misipode Dosu ti wọn ri pẹlu baba naa kẹyin lo ran an sọrun ọsan gangan.

Ko le pẹ mọ ti wọn yoo fi gbe e lọ si kootu fun ẹsun ipaniyan, gẹgẹ bi CP Edward Ajogun, kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ṣe paṣẹ.

Leave a Reply