Wọn ti mu eeyan mẹta lori iku Dapọ Ọjọra, ẹgbọn iyawo Bukọla Saraki, ti wọn lo yinbọn para ẹ

 Jide Alabi

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe ọwọ ti tẹ awọn kan bayii lori iku ojiji to pa Dapọ Ọjọra lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, bo tilẹ jẹ pe niṣe lawọn eeyan kan sọ pe funra ẹ lo yinbọn para ẹ.

Ohun ti awọn ọlọpaa sọ ni pe ọkan lara awọn oṣiṣẹ to n ba wọn mojuto ile ni ẹjọ ọ jẹ nipa iku to pa ọkunrin yii, bakan naa ni wọn sọ pe ẹka ọtẹlẹmuyẹ ni teṣan ọlọpaa to wa ni Panti, Yabaa, l’Ekoo, ti bẹrẹ iwadii wọn.

Agbẹnusọ fun awọn ọlọpaa l’Ekoo, Muyiwa Adejobi, ninu ọrọ ẹ sọ pe awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti lọ sile ọkunrin naa, bẹẹ ni wọn ti kẹẹfin awọn nnkan kan to nilo alaye gidi nipa bo ṣe jẹ gan-an, eyi ti yoo ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn, ati pe pẹlu bi ọrọ ṣe ri yii, o ti di dandan ki awọn eeyan kan dahun awọn ibeere kan to ti n ṣuyọ bayii.

Ni gbogbo ọjọ Abamẹta, Satide, ti iroyin ọhun gbalu, ibọn ni wọn sọ pe Dapọ Ọjọra yin lu ara ẹ ninu ile to n gbe ni Ikoyi, l’Ekoo, ti ọkunrin naa si dagbere faye loju-ẹsẹ.

Lojiji ni wọn sọ pe awọn eeyan ti wọn jọ n gbe gbọ iro ibọn, nigba ti wọn yoo si fi sare de ibi to wa, ninu agbara ẹjẹ ni wọn ti ba Dapọ.

Ni kete ti iṣẹlẹ ọhun ti waye loriṣiriiṣii iroyin ti gba igboro, bi awọn kan ṣe n sọ pe niṣe ni ẹgbọn Toyin Saraki yii yinbọn funra ẹ lori, bẹẹ lawọn mọlẹbi n sọ pe ki i ṣe pe o para ẹ o, aṣita ibọn lo pa a.

AKEDE AGBAYE tun gbọ pe ni nnkan bii ọdun mẹsan-an sẹyin ni Ọtunba Adekunle Ọjọra, eni ti i ṣe baba ọkunrin to yinbọn para ẹ yii ti kọkọ padanu ọmọ ẹ ọkunrin ti wọn pe orukọ ẹ ni Gboyega Ọjọra, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Gbẹgi. Bakan naa ni wọn tun sọ pe ori ti kọkọ ko Dapọ yii yọ lasiko to ni ijanba pẹlu ọkada olowo nla kan ti wọn n pe ni Power Bike ni nnkan bii ọdun meloo kan sẹyin.

 

Sẹnetọ Bukọla Saraki, ẹni ti i ṣe ana oloogbe yii naa ti ti dupẹ lorukọ ẹbi, lọwọ awọn to ṣedaro pẹlu wọn atawọn ọlọpaa paapaa ti wọn ti tara bọ iwadii iku to pa ọkunrin yii lori ikanni abayẹfo ẹ. Bakan naa lo sọ pe ẹbi yoo kede bi eto isinku Dapọ Ọjọra yoo ṣe lọ laipẹ yii.

 

Leave a Reply