Wọn ti mu Johnson to n fi aṣọ ṣọja jale l’Ogudu

Faith Adebọla, Eko

 

 

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lawọn ti fi pampẹ ofin gbe afurasi ọdaran kan, Johnson Godday, aṣọ ṣọja lo wọ sọrun, ṣugbọn a-lọ-kolohun-kigbe ẹda ni.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lọwọ ba jagunlabi naa ni nnkan bii aago mọkanla oru, nibi to ti ṣakọlu sawọn eeyan kan ti wọn n dari rele wọn lati ibiiṣẹ ounjẹ oojọ wọn.

Bi Olumuyiwa Adejọbi, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, ṣe fidi ẹ mulẹ, ọkan lara awọn ti Johnson ṣakọlu si, to si tun ja lole, ni Ọgbẹni Nwanga Onyebuchi, to n gbe Ojule kẹrinlelogun, Opopona Bayọ Ọshinọwọ, Ogudu, nipinlẹ Eko.

Nwanga lo ṣalaye fawọn ọlọpaa pe oun atawọn ọrẹ oun bii mẹta lawọn jọ bọọlẹ ninu kẹkẹ Maruwa nikorita Emmanuel, onikaluku si kọri sọna ile ẹ, awọn n fẹsẹ rin lọ, afi bawọn ṣe ri awọn ọkunrin meji kan lori ọkada, ti wọn n sare buruku bọ lọdọ awọn, aṣọ ṣọja lawọn mejeeji wọ, bi wọn ṣe bẹ gija mọ awọn niyẹn, wọn bẹrẹ si i kọ lu awọn pẹlu igbaju igbamu, wọn si gba foonu Infinix 5 smartphone oun, ni wọn ba sa lọ, boya nigba ti wọn ri i pe ariwo, ‘ẹ jọọ, ẹ jọọ’ tawọn n pa ti n lọ soke ju.

O ni ibi tiṣẹlẹ yii ti waye ko fi bẹẹ jinna sibi tawọn ọlọpaa kan lati teṣan Ogudu maa n duro si, lawọn ba sare kegbajare lọọ ba wọn, oju ẹsẹ si lawọn ọlọpaa naa mu wọn le pẹlu mọto wọn.

Ṣa, ọwọ ba Johnson, oun lo jokoo sẹyin lori ọkada, ibi ti wọn ti n du ki wọn sa m’awọn ọlọpaa lọwọ ni wọn loun ti ja bọ, ti wọn fi ri i mu, ṣugbọn ekeji ẹ ti wọn loun naa wọṣọ ṣọja gbe ọkada sa lọ.

Kọmiṣanna ọlọpaa, Hakeem Odumosu, ti paṣẹ pe ki wọn fi Johnson ṣọwọ sọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, wọn si ti n ṣiṣẹ iwadii. Wọn lawọn ọlọpaa ti n tọpasẹ ẹni

Leave a Reply