Wọn ti mu Kazeem to pa ọmọ ẹgbẹ okunkun ẹgbe ẹ ni Ṣagamu

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Suleman Kazeem lorukọ ọkunrin ti ẹ n wo yii,ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye ni, ni Ṣagamu. Ọjọ keje, oṣu kefa yii, lọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ ẹ, lẹyin ti wọn lo pa ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ ti wọn pe orukọ tiẹ ni Ajẹkunrin.

Awọn eeyan lo pe DPO teṣan Ṣagamu lọjọ naa, pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye ati Ẹyẹ ti bẹrẹ rogodiyan lagbegbe  Latawa, wọn ko si jẹ ki ẹnikẹni le jade lọ sibi to yẹ ki wọn lọ.

CSP Okiki Agunbiade ni DPO teṣan naa, oun atawọn ikọ rẹ gba ibi ti wọn ti n ja naa lọ. Nigba ti wọn debẹ ni wọn ri i pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ti pa ẹnikan toun naa jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ, ẹni ti wọn pe orukọ ẹ ni Ajẹkunrin.

Koda, ki i ṣe pe wọn pa a lasan, wọn tun ge ọwọ rẹ mejeeji lọ ki wọn too sa lọ.

DPS Abimbọla Oyeyẹmi to fiṣẹlẹ naa sita ṣalaye pe niṣe lawọn ọlọpaa atawọn fijilante, wa awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa kiri titi ti wọn fi ri Suleman Kazeem yii mu, wọn si ni olori awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye ni.

Awọn ọlọpaa ba ibọn oloju meji to jẹ ti ibilẹ lọwọ rẹ, wọn ba ọta ibọn kan ti wọn ko ti i yin pẹlu, ati foonu kan.

Wọn ti taari ọkunrin yii sẹka itọpinpin, gẹgẹ bi CP Edward Ajogun ṣe paṣẹ.

Leave a Reply