Wọn ti mu marun-un ninu awọn to n jiiyan gbe l’Ọbada-Oko

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ṣinkun lọwọ ọlọpaa, fijilante atawọn ọlọdẹ ibilẹ, ba marun-un ninu awọn ajinigbe to n pitu buruku l’Ọbada-Oko, l’Abẹokuta, iyẹn lẹyin ti olobo ta awọn agbofinro pe ọkada meji ko awọn kan wọnu igbo ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ, lagbegbe Ẹlẹja, l’Ọbada-Oko.

Awọn ọlọpaa pe awọn ikọ alaabo So Safe atawọn fijilante ibilẹ pẹlu awọn ọlọdẹ, wọn jọ wọgbo ọhun gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa Ogun ṣe wi. Ninu igbo naa lọwọ wọn si ti ba Aliu Manya, Usman Abubakar, Abayọmi Ọlayiwọla, Nasiru Muhammed ati Bello Usman.

Nigba tawọn ọlọpaa n ba iwadii wọn lọ ni ọkan ninu awọn eeyan ti wọn ti ji gbe ri l’Ọbada-Oko, nawọ sawọn eeyan naa pe awọn ti wọn ji oun gbe ree. Bakan naa ni ẹgbọn rẹ to gbe owo lọ fawọn ajinigbe naa ki wọn too tu ẹni ti wọn ji gbe yii silẹ tun nawọ si meji ninu awọn marun-un yii pe awọn ni wọn gbowo toun gbe lọ sinu igbo naa lọwọ oun.

Awọn nnkan tawọn ọlọpaa ba lọwọ awọn marun-un yii ni oogun oloro tijọba ti fofin de bii Tramadol, igbo, ada mẹta, ọkada meji ti nọmba wọn jẹ  MEK 504 VC ati ODE 423 VC,  foonu mẹfa ati ẹgbẹrun mẹtalelaaadọrin naira (73,000)

Bi wọn ṣe ri wọn mu yii, ẹka ti wọn ti n gbọ ẹjọ awọn ajinigbe ni wọn ko wọn lọ gẹgẹ bi aṣẹ CP Lanre Bankọle.

Ọga ọlọpaa naa si rọ awọn araalu pe bi wọn ba ti kẹẹfin awọn onirin ifura bii eyi, ki wọn tete maa fi to ọlọpaa leti. Bakan naa lo ni kawọn eeyan oun ṣiṣe lori bi wọn yoo ṣe ri awọn yooku to ṣee ṣe ki wọn fara pamọ sinu igbo naa ri.

Leave a Reply