Wọn ti mu meji ninu awọn to yinbọn pa Iya Maria n’Ijoun

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Lẹyin oṣu meji ti awọn ajinigbe ya bo agbegbe kan ti wọn n pe ni Ijoun, nijọba ibilẹ Ariwa Yewa, ti wọn si yinbọn pa obinrin kan, Hannah Fagbohun, ti wọn ji ọmọ ẹ, Maria Fagbohun, gbe pẹlu, ọwọ ọlọpaa ti ba meji ninu awọn apaayan naa.

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2020, ni ikọ ajinigbe mẹfa da Maria Fagbohun, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn(25) lọna nigba to n pada sile lati sọọbu rẹ to ti n ta ọti ati atẹ.

Bi wọn ṣe ki i mọlẹ ti wọn n gbe e lọ lo bẹrẹ si i pariwo, eyi ti iya rẹ gbọ to fi tara abiyamọ jade, toun naa si n ke sawọn eeyan pe ki wọn ṣaanu oun, ki wọn ma jẹ kawọn ajinigbe ji ọmọ oun gbe lọ.

Ariwo Iya Maria to fẹẹ ba nnkan jẹ fawọn ajinigbe naa lo jẹ ki wọn yinbọn saarin awọn to fẹẹ gba Maria silẹ, iya rẹ gangan, Hannah Fagbohun, ẹni aadọta (50) ọdun nibọn naa ba, ẹsẹkẹsẹ ni iya naa si dagbere faye, awọn ajinigbe naa si gbe Maria lọ ko too di pe o jajabọ lọwọ wọn pẹlu iranlọwọ Ọlọrun ati atilẹyin awọn eeyan.

Lẹyin iku Iya Maria lọwọ ba ọkan ninu awọn afurasi naa, ẹni ti wọn pe orukọ ẹ ni Jimọh Fayẹmi. Ikọ ọlọpaa to n ri si ijinigbe ko sinmi lẹyin eyi, wọn tun tanna wa ẹnikan torukọ tiẹ n jẹ James Arowolo, toun naa jẹ ọkan ninu awọn to ji Maria gbe, ipinlẹ Ekiti ni wọn ti mu un.

Awọn mejeeji naa lo waa jẹwọ pe ẹnikan to n jẹ Ade ati ọrẹ ẹ ti wọn n pe ni Doctor ti wọn n gbe laduugbo kan naa pẹlu Maria lo ran awọn pe kawọn lọọ lu u ni jibiti owo nla.

Wọn ni nigba ti ọgbọn jibiti naa ko jẹ ọmọbinrin yii lawọn kuku pete ati ji i gbe, kawọn le gba owo nla tawọn fẹẹ gba lọwọ ẹ naa, ati kawọn le beere owo itusilẹ lọwọ awọn eeyan rẹ.

Nigba tọwọ ba wọn, ibọn mẹta lawọn ọlọpaa sọ pe awọn ba lọwọ wọn, ọta ibọn mejila pẹlu iboju ( face mask)

CP Edward Ajogun ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa wa awọn tọwọ ko ti i ba ninu awọn eeyan naa ri, ki wọn si ko awọn meji yii lọ si kootu fun ẹsun ijinigbe ati ipaniyan.

Leave a Reply