Wọn ti mu obinrin yii o, awọn alaboyun rẹpẹtẹ ni wọn ba nileeṣẹ to ti n ta ọmọ ìkókó

Adewale Adeoye

Awọn ọdọmọdebinrin ti wọn wa nipo iloyun, ti oyun wọn si wa ni ipele oriṣiiriṣii lawọn ọlọpaa agbegbe Aluu, nijọba ibilẹ Ikwerre, nipinlẹ Rivers, sọ pe awọn ti ko kuro nileeṣẹ kan bayii ti wọn gbagbọ pe ẹni to ni in n fawọn ọmọ ti wọn ba bi sibẹ ṣe okoowo ni.

Awọn ọdọbinrin ọhun tọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun si ọgbọn ọdun lọ, ni awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ naa sọ pe awọn yoo ṣẹwadii daadaa nipa ohun to gbe wọn debi ti wọn ti ri gbogbo wọn ko, ko too di pe awọn yoo mọ ohun tawọn maa ṣe pẹlu ọrọ wọn bayii.

ALAROYE gbọ pe awọn araalu to ri kurukẹrẹ awọn eeyan ọhun lo lọọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa agbegbe ibi tileeṣẹ buruku naa wa leti, tawọn agbofinro ọhun si tara ṣaṣa lọ sibẹ, ti wọn fọwọ ofin mu Abilekọ Akudo Azoroh, ẹni to nileeṣẹ ọhun pe ko waa sọ tẹnu rẹ nipa ohun to n fawọn alaboyun ti wọn ba lọdọ re ṣe lai jẹ pe o gba iwe aṣẹ kankan lọdọ awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ naa rara.

Obinrin yii ni ki i ṣe pe oun lọọ fipa mu awọn ọdọbinrin naa wa sileeṣẹ oun rara, o ni funra wọn ni wọn fẹsẹ ara wọn rin waa ba oun, toun si n ṣetọju wọn daadaa, ati pe, awọn idile alayọ ti wọn n woju Ọlọrun Ọba fun ọmọ loun maa n ta awọn ọmọ tawọn ọdọmọbinrin naa ba bi fun.

Akudo ni, ‘Mi o fipa mu awọn alaboyun gbogbo ti wọn ba lọdọ mi yii rara, funra wọn ni wọn fẹsẹ ara wọn rin wa sọdọ mi pe ki n ṣaanu awọn.

Oniruuru nnkan lo gbe wọn wa sọdọ mi, awọn kan wa to jẹ pe wọn ko mọ ẹni ti wọn loyun fun rara, bẹẹ lawọn kan wa to jẹ pe ẹni to fun wọn loyun ko gba oyun naa lọwọ wọn, gbara ti wọn ba ti bimọ inu wọn tan la maa ti gba a lọwọ wọn, ti ma a si fun wọn lowo to jọju daadaa. Mo maa n fun awọn mi-in to ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin Naira (N800,000), nigba tawọn mi-in maa n gba ju bẹẹ lọ lọwo mi. Irufẹ ọmọ ti wọn ba tun bi lo maa sọ iye owo ti ma a fun wọn nigba mi-in. Ọmọ ọkunrin jawo daadaa ju ọmọbinrin lọ gan-an.

Mi o ki i gbe awọn ọmọ naa fawọn to n lo wọn fi ṣoogun owo rara, awọn toju ọmọ pọn gidi ni mo maa n gbe awọn ọmọ naa fun nigba ti wọn ba wa sọdọ mi. Bakan naa lo jẹ pe mi o lọkunrin kankan lọdọ to n fawọn ọdọbinrin ọhun loyun rara, awọn ni wọn maa n gbe oyun won wa lati ita.

O tẹ siwaju pe o kere tan, awọn lọkọ-laya bii mẹfa tabi ju bẹẹ lọ loun ti gbe awọn ọmọ fun, miliọnu kan aabọ Naira lo ni oun maa n gba lọwọ awọn ẹni ti wọn ba n fẹ ọmọ lati ọwọ oun.

Nigba tawọn oniroyin n fọrọ wa awọn ọdọbinrin gbogbo ti wọn fọwọ ofin mu lọdọ Akudo yii ni ọpọ lara wọn ti jẹwọ pe loootọ, awọn funra awọn lawọn wa sọdọ Akudo yii pẹlu ero lati ta ọmọ tawọn ba bi fun un, ko le fawọn lowo lati maa fi ba igbesi aye awọn lọ, wọn ni koko ohun to jẹ kawọn maa ta awọn ọmọ naa ni pe awọn ko lagbara lati maa tọju wọn  tawọn ba bi wọn silẹ tan.

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Rivers, C.P Polycarp Nwonyi, ti kilo fawọn ọbayejẹ gbogbo ti wọn fipinlẹ naa ṣebugbe bayii  pe ki wọn fiwa radarada ọwọ wọn yii silẹ, tabi ki wọn ṣetan lati fimu kata ofin bọwọ ba tẹ wọn.

Bakan naa lo ṣeleri pe awọn yoo foju Akudo bale-ẹjọ lati lọọ kawọ pọyin rojọ niwaju adajọ lori ohun to ṣe yii.

Leave a Reply