Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn afurasi oníjìbìtì mẹta ni wọn ti wa lakolo ajọ sifu difensi, nipinlẹ Ondo, lori ọkan-o-jọkan ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Awọn afurasi ọhun, Bọlọfinde Ojo Ọdunayọ, ẹni ọdun mẹtalelogun, Bọlọfinde Durotifa, ẹni ọdun mọkandinlogoji, Ibrahim Saheed, ẹni ọdun mọkanlelogun ati Idowu Oluwaṣeun, ọmọ ogun ọdun ni wọn fẹsun kan pe wọn ko niṣẹ meji ti wọn n ṣe ju ki wọn maa lu awọn oni POS ni jibiti lọ.
Alukoro ajọ naa nipinlẹ Ondo, Daniel Aidamenbor, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si wa ni awọn mẹta lọwọ awọn ṣi tẹ na, nigba ti iwadii ṣi n lọ labẹnu lati ri ẹni kẹrin wọn, iyẹn Bọlọfinde Ojo Ọdunayọ, mu.
O ni ijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, ni Ojo, Durotifa ati Oluwaṣeun ti wa, ṣugbọn Saheed nikan lo jẹ ọmọ bibi ilu Ọwọ, n’ijọba ibilẹ Ọwọ, ninu wọn.
Aidamenbor ni ohun tawọn onijibiti ọhun maa n ṣe ni ki wọn lọọ ba oni POS kan pe awọn fẹẹ gbowo, lẹyin eyi lo ni awọn funra wọn yoo tun mori le ọna banki ti wọn n lo lati lọọ ṣalaye fun wọn pe ṣe ni wọn mọ-ọn-mọ yọ owo awọn niyọkuyọ lai ri owo naa gba.
O ni banki wọn yoo kọkọ da owo ti wọn ni wọn yọ naa pada fun wọn ki wọn too tun ti POS naa pa nitori erongba pe iṣẹ jibiti lẹni to ni in n fi i ṣe.
O ni ohun ti wọn ṣe fun oni POS kan, Oguntomiloye Taiwo, ree ti awọn banki fi ti ẹrọ to fi n ṣowo naa pa.
O ni ọkunrin yii lo wa si ọfiisi awọn lati waa fẹjọ sun ki ọwọ too pada tẹ mẹta ninu awọn ogboju onijibiti naa lẹyin ọpọlọpọ iwadii ti awọn ṣe.
Durotifa to jẹ ọkan lara awọn afurasi ọhun lo ni o ti jẹwọ fun awọn lori ọna ti wọn n gba ṣiṣẹ ibi ti wọn yan laayo.
Gbogbo awọn tọwọ tẹ naa lo ni awọn yoo foju wọn bale-ẹjọ ni kete tí iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn mu wọn fun.