Wọn ti mu ọlọpaa to yinbọn pa Mọnsurat n’Ijẹṣatẹdo

Faith Adebọla, Eko

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti rawọ ẹbẹ sawọn mọlẹbi ọmọbinrin ẹni ọdun mejidinlogun kan, Mọnsurat Ojuade, ti wọn lọlọpaa aribọnyọ kan yinbọn pa lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii lati jeburẹ, wọn lawọn ti ri ọlọpaa ọhun, awọn si ti fi i sahaamọ awọn afurasi ọdaran.

Ninu atẹjade kan ti Agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa Eko, CSP Adekunle Ajiṣebutu, fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lori iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun lo ti ni iyalẹnu lo jẹ fawọn lati gbọ pe ọkan lara awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lati Panti, Yaba, ti wọn lọọ ṣiṣẹ iwadii kan lori afurasi adigunjale kan lagbegbe Ijẹṣatẹdo, nipinlẹ Eko, lo huwa laabi ọhun, wọn loun lo tawọ sadọdọ ibọn lai bikita, to si ṣe bẹẹ da ẹmi ọmọbinrin to n lọ jẹẹjẹ ẹ yii legbodo.

Adekunle ni gbogbo igbiyanju awọn agbofinro lati doola ẹmi Mọnsurat lo ja si pabo, bi wọn ṣe n fi mọto ọlọpaa gbe e lọ sọsibitu lọmọbinrin naa dagbere faye pẹlu irora.

Kọmiṣanna ọlọpaa Eko ti gbọ siṣẹlẹ yii, o si kẹdun gidi pẹlu awọn obi ati mọlẹbi oloogbe.

Bo tilẹ jẹ pe wọn o fẹẹ darukọ ọlọpaa to ṣaṣemaṣe ọhun, bẹẹ ni wọn o ti i fi fọto ẹ lede, awọn kan ti wọn mọ ọlọpaa naa sọ pe Sajẹnti Samuel Phillips lo n jẹ.

Odumosu ni oun rawọ ẹbẹ gidi si awọn mọlẹbi oloogbe naa pe ki wọn fiye denu, o loun fi da gbogbo olugbe ipinlẹ Eko loju pe awọn ti mu ọlọpaa ti wọn lo ṣiṣẹkiṣẹ yii, awọn si maa ri i pe idajọ ododo waye, ko ni i ṣai fimu kata ofin bo ṣe yẹ.

O loun ti paṣẹ pe ki igbẹjọ akọkọ waye gẹgẹ bii ilana ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn maa n tẹle tawọn agbofinro ba huwakiwa, lẹyin tawọn ba si ti le e kuro lẹnu iṣẹ ọlọpaa ni yoo balẹ silẹ-ẹjọ lati gba idajọ to ba tọ si i.

Leave a Reply