Faith Adebọla, Eko
Awari ti obinrin n wa nnkan ọbẹ lawọn ọlọpaa fi ọrọ afurasi ọdaran kan, Eze Aiwansone, ṣe, ọlọpaa ti wọn fẹsun kan pe o fibinu yinbọn mọ afẹsọna ẹ, Joy Eze, lori ọrọ ti ko to nnkan to dija laarin wọn, to si sa lọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Ademuyiwa Adejọbi, lo ṣalaye f’ALAROYE lọfiisi rẹ n’Ikẹja pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọse yii lawọn ri i mu, ẹgbọn rẹ kan toun naa jẹ inspẹkitọ nipinlẹ Eko lo waa fa a kalẹ fawọn ọlọpaa ni olu ileeṣẹ wọn to wa n’Ikẹja.
Adejọbi ni ẹka ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ CID to wa ni Panti, Yaba, ti n ba iṣẹ iwadii lọ lori ọrọ yii tẹlẹ, o ni bọwọ si ṣe tẹ Sajẹnti Eze yii yoo mu ki ọrọ ọhun tete lojuutu.
Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii ọsẹ meji ni ALAROYE gbe iṣẹlẹ to waye ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ ọjọ kẹjọ, oṣu kẹwaa, naa.
Aigbọra-ẹni-ye ranpẹ kan ni wọn lo waye laarin ọlọpaa yii ati Joy, nigba to n sin ọmọbinrin naa lọ sibudokọ Salvation, lagbegbe Ọpẹbi, n’Ikẹja, nibi tiyẹn ti fẹẹ wọ mọto pada sile to n gbe ni Ọgba ni Sajẹnti Eze fi tawọ si adọdọ ibọn to gbe kọrun, lo ba yin in fun afẹsọna rẹ, ṣugbọn ori ko o yọ, ẹnu ni ibọn naa ti ba a, niṣe lẹnu ẹ faya, ti ẹjẹ si bo o, ki wọn too sare gbe e lọ sọsibitu.