Wọn ti mu Suliya o, lati Ilobu lo ti lọọ ji ewurẹ l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Ọṣogbo

Awọn oṣiṣẹ ajọ sifu difẹnsi nipinlẹ Ọṣun ti tẹ iyaale ile kan, Suliyat, ẹni ti wọn sọ pe o ji ewurẹ kan niluu Oṣogbo.

Atẹjade kan lati ọdọ Agbẹnusọ ajọ naa, Daniel Adigun, sọ pe agbegbe Konda, niluu Ilobu, ni obinrin naa n gbe, ṣugbọn agbegbe Ayepe, niluu Oṣogbo, lo ti lọọ ji ewurẹ naa.

Adigun ṣalaye pe o ti pẹ ti awọn nnkan ọsin ti n poora laduugbo naa, ti wọn si maa n fi iṣẹlẹ naa to awọn agbofinro leti.

Ṣugbọn lọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla, ọdun yii, ni Suliya lọ sibẹ, to si ji ewurẹ dudu nla kan, bo ṣe n mu un kuro ninu adugbo ni ẹnikan pade rẹ lọna, ti wọn si beere ibi to ti ri ewurẹ ọhun.

Nigba ti Suliya n kalolo, ti ko si ri ọrọ kankan sọ ni awọn araadugbo bẹrẹ si i na an, ọpẹlọpẹ awọn sifu difẹnsi ti wọn tete debẹ, awọn ni wọn gbe e kuro laarin wọn lọ si ọfiisi wọn.

Lọdọ wọn ni afurasi naa, ẹni ọgbọn ọdun, ti jẹwọ pe loootọ loun ji ewurẹ naa.

Adigun sọ siwaju pe lẹyin iwadi ni obinrin naa yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply