Wọn ti mu Yakubu to ja ọkada Nasiru gba ni Lẹkki

Faith Adebọla, Eko

 Pako bii maaluu to r’ọbẹ, lọmọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan torukọ ẹ n jẹ Yakubu Hammar n wo, lasiko to ko sokolo ọlọpaa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, iyẹn lẹyin to fibọn gba ọkada Ọgbẹni Nasiru Abubakar, lagbegbe Lẹkki, l’Ekoo.

Ọkunrin kan tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ sọ f’Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa pe ọpẹlọpẹ awọn ọlọkada mẹfa ti wọn kun awọn ọlọpaa ikọ Rapid Response Squard (RRS), lọwọ, awọn ni wọn le afurasi ole yii nigba to n sa lọ pẹlu ọkada to ji.

Yakubu fẹnu ara ẹ ṣalaye pe niṣe loun da ọlọkada naa duro pe ko gbe oun lati ibudokọ General Paint lọ si ibudokọ Chevron, awọn si jọọ dunaa dura owo si ẹẹdẹgbẹta Naira (N700). Ṣugbọn bi awọn ṣe de agbegbe Too-geeti keji loun da ọlọkada naa duro pe oun  fẹẹ sare ṣegbọnsẹ, aṣe o fẹẹ dọgbọn lọọ mu nnkan ija rẹ ni.

Wọn ni ko ju iṣẹju meji lo ba tun pada de pe oun ko ri igbẹ naa ya, ko jẹ kawọn maa lọ. Bi ọlọkada ṣe fẹẹ kiiki ọkada ẹ ni jagunlabi ba fi ankaṣiifu funfun kan bo o loju, o si faṣọ naa fun un lọrun pinpin bii ẹni fẹẹ pa a, lo ba taari ẹ kuro lori ọkada yakata, o bẹna si ọkada ẹ, o n sa lọ.

Bi Abubakar ṣe n lọgun ‘ole, ole,’ lo mu kawọn ọlọkada ẹgbẹ ẹ duro, iboosi naa lo si mu kawọn ọlọpaa RRS to n ṣe patiroolu gbọ, ni wọn ba gba fi ya Hammar.

Nigba t’Ọlọrun maa mu afurasi adigunjale yii, okun tọtu ọkada naa ja lojiji, ibi to si ti n dọgbọn lati so o, laimọ pe wọn n le oun bọ, ni wọn ka a mọ nitosi ibudokọ Chisco.

Awọn ọlọkada ti wọn le e mu sọ pe ko ti i ju oṣu kan ti afurasi ole yii deluu Eko, wọn ni lagbegbe Oke-Ọya lo ti wa.

Ṣa, atoun ati ọkada to ji gbe ti wa lahaamọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, ti wọn n ṣe iwadii. Wọn lọkunrin naa ti n ṣalaye ara ẹ fun wọn.

Leave a Reply