Adajọ ti ran Genesis, wolii Sẹlẹ lẹwọn nitori ẹsun jibiti

Jide Alabi

Ile-ẹjọ giga kan niluu Abuja ti ju olori ṣọọsi Sẹlẹ kan, Global Genesis Parish, Dele Ogundipẹ, si ẹwọn ọdun kan, ẹsun ti wọn si fi kan an ni pe o lu obinrin oniṣowo kan ni jibiti miliọnu mọkanla naira.

Adajọ Ọlabisi Akinlade, ti ile-ẹjọ giga kan to wa niluu Abuja, lo ran Wolii Israel Dele Ogundipe, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Israel Genesis, lẹwọn yii.

Ninu ẹsun koko meje ti wọn ka si i lọrun, adajọ naa sọ pe meji nibẹ lọkunrin naa jẹbi ẹ, nigba to da marun-un yooku nu pe ko si ẹri gidi lati fi gbe e lẹsẹ.

Obinrin kan to maa n ṣowo ile kikọ ati ilẹ rira, to n gbe niluu oyinbo, Arabinrin Ọlaide Williams-Oni, lo wọ Dele Ogundipẹ lọ sile-ẹjọ, ẹsun to si fi kan an ni pe ọkunrin naa fi ọgbọn gba miliọnu mọkanla lọwọ oun pẹlu ileri pe oun yoo ba oun ra awọn dukia kan to jẹ mọ ilẹ ni Naijiria.

Lati ọdun 2007 ni ALAROYE gbọ pe ọrọ yii ti wa nile-ẹjọ, ati pe ọdun 2002 ti obinrin yii wa si Naijiria lo sọ pe awọn pade nigba ti aburo rẹ kan mu un lọ si ṣọọṣi Dele Genesis fun eto adura.

O ni nibi tawọn ti pade niyẹn o, ti ọkunrin to pe ara ẹ ni ojiṣẹ Ọlọrun yii si ṣeleri lati ran oun lọwọ lati ra awọn dukia ọhun, ṣugbọn ti ileri to ṣe naa pada ja si jibiti.

Ọdun 2007 ni igbẹjọ kọkọ waye lori ọrọ naa, latigba naa si ni wọn ti n fa a, ki Adajọ Ọlabisi Akinlade too paṣẹ pe ki wọn lọọ sọ ọkunrin naa sẹwọn ọdun kan bayii, nitori to jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an ọhun.

 

One thought on “Adajọ ti ran Genesis, wolii Sẹlẹ lẹwọn nitori ẹsun jibiti

  1. Botile je bi oroyi se ri in yi kosi eni tomo tan bi kin se olorun oyeki agba owo na pada lowo prophet oladele nitori pe ayere masi sile ninu ijo olorun ati ninu aiye opo eni yan

Leave a Reply