Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin ọpọlọpọ wahala lọsan-an ati aisun loru, awọn agbofinro ti tu ṣọja ti awọn ẹruuku ji gbe n’Ibadan silẹ ninu igbekun.
Aṣeyọri ọhun waye lẹyin ajumọṣepọ iṣẹ aṣekara laarin awọn ọlọpaa atawọn ikọ eleto aabo bii Amọtẹkun, fijilante atawọn ọdẹ ibilẹ nijọba ibilẹ Oluyọle, n’Ibadan.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, nibi ti awọn eeyan naa ti n rin lọ ninu afonifoji ibẹru lẹyin ti wọn ti kuro nigbekun awọn ajinigbe, ni wọn ko sọwọ awọn ọlọpaa to ti n wa wọn kiri inu igbo naa tẹlẹ lati ijẹrin. Nitosi ile-ẹja kan ti wọn n pe ni Triton Fish Company, lagbegbe Ogunmakin, n‘Ibadan, lawọn agbofinro ti ri wọn.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, DSP Adewale Ọṣifẹṣọ, ṣapejuwe iṣẹlẹ yii gẹgẹ bii aṣeyọri ninu akitiyan ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ yii, CP Ngozi Onadẹkọ, lati gbogun ti iwa ọdaran.
O ni “Nitori ba a ṣe wa awọn ọdaran yẹn lo jẹ ki awọn ajinigbe tu awọn ti wọn mu silẹ.” Nipa bẹẹ, CP Ngozi Onadeko ti rọ gbogbo ọmọluabi eeyan nipinlẹ Ọyọ lati maa fi awọn iṣẹlẹ iwa ọdaran to awọn ọlọpaa leti lasiko, ki eto aabo le tubọ dan mọran si i fun tẹru-tọmọ
Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ aarọ ọjọ kejila, oṣu kẹta, ọdun 2021 yii, lawọn ọbayejẹ kan ji obinrin ṣọja kan, Bọlanle Ogunrinde, atawọn meji mi-in ti wọn n jẹ Abọsẹde Adebayọ ati Abilekọ Ọkẹowo Theresa gbe labule ti wọn n pe ni Onipẹẹ, lọna to ti Ibadan lọ s’Ijẹbu-Ode, nigba tawọn eeyan naa n ti Ibadan lọ sọna Ijẹbu-Ode pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ Toyota wọn ti nọmba rẹ jẹ AGL 66 FY.
Lati ọjọ Mọnde ọhun lawọn agbofinro ko ti sun, ti wọn ko wo, lori itọpinpin awọn olubi ẹda naa.
Ṣaaju ni AC Ops, iyẹn igbakeji ọga agba ọlọpaa to n mojuto iṣọwọ-ṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, ACP Gbenga Ojo sọ pe “Gẹgẹ ba a ṣe mọ, awọn iṣẹlẹ ijinigbe waye lẹnu ọjọ mẹta yii lọna Ibadan si Ijẹbu-Ode, eyi lo jẹ ka fọn awọn ọlọpaa sita pẹlu iranlọwọ awọn fijilante atawọn ọdẹ ibilẹ.
O ni loorekoore lawọn ọlọpaa yoo maa kaakiri gbogbo inu igbo bayii lati ri i pe awọn ọdaran ko ribi fara mọ ṣiṣẹ ibi níbikíbi n’Ibadan ati kaakiri ipinlẹ Ọyọ.