Wọn ti ri awọn akẹkọọ Fasiti Ọlabisi Ọnabanjọ meji ti wọn ji gbe lọ pada

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lẹyin ọjọ meji ti wọn lo ni akolo awọn ajinigbe, awọn akẹkọọ Yunifasiti Ọlabisi Ọnabanjọ meji ti awọn ajinigbe ji gbe lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ti gba ominira.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fidi ẹ mulẹ  fun akọroyin wa ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ kọja ogun iṣẹju, alẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹta yii, pe awọn ọmọbinrin meji naa, Adeyẹmọ Precious ati Oyefule Abiọla, wa lọdọ awọn boun ṣe n ba wa sọrọ naa.

Alukoro sọ pe to ba di laaarọ ọjọ keji ti i ṣe Ọjọruu, oun yoo fi atẹjade ti yoo ṣalaye irin-ajo awọn ọmọ naa sita lẹkun-unrẹrẹ sita.

ALAROYE gbọ pe miliọnu meji naira lobi awọn ọmọ naa san ki wọn too ri wọn gba pada.

Leave a Reply