Wọn ti ri awọn ọga ọlọpaa mẹsan-an ti wọn ji gbe gba pada

Jide Alabi

Ileeṣẹ ọlọpaa ti kede pe wọn ti tu awọn ọga ọlọpaa ti wọn ṣẹṣẹ gba igbega lẹnu iṣẹ wọn tawọn janduku ajinigbe kan ji gbe laipẹ yii silẹ bayii.

Ọjọ kẹjọ, oṣu kọkanla yii, ni wọn ji wọn gbe nipinlẹ Katsina, lasiko ti wọn n lọ si ilu Gusau, nipinlẹ Zamfara.

ALAROYE gbọ pe Maiduguri, nipinlẹ Borno, lawọn eeyan yii ti kuro, ati pe niṣe ni wọn fẹẹ lọọ wọṣẹ  ni Zamfara, ki wọn too ko sọwọ awọn ajinigbe, tawọn yẹn si n beere fun ọgọrun-un miliọnu naira lọwọ awọn mọlẹbi wọn.

Ilu kan ti wọn n pe ni Kankara ati Sheme, nipinlẹ Katsina, lọwọ ti tẹ wọn, laarin oru ninu mọto akero ti wọn wọ.

A gbọ pe bii oloogun lawọn ajinigbe ọhun ṣe mura, ṣugbọn janduku paali ni wọn.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, DCP Frank Mba, sọ pe loju ẹsẹ tawọn ti kẹẹfin pe wọn ti ji wọn gbe lawọn naa ti dihamọra ogun, tawọn si ti gba wọn kalẹ lọwọ awọn oniṣe ibi ọhun.

Bakan naa lo fi kun un pe ileeṣẹ ọlọpaa mọ-ọn-mọ ma sọ ohukohun latijọ yii ni, ki awọn ma baa sọ aṣiri gbogbo igbesẹ awọn lati ri awọn ẹṣọ agbofinro ọhun gba pada sita.

O ni mẹsan-an gan-an ni wọn, gbogbo wọn lawọn si ti gba pada bayii.

Meji ninu awọn ẹṣọ agbofinro ọhun lo sọ pe wọn n gba itọju bayii, nigba ti awọn meje yooku wa nibi ti wọn ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo lori ohun to ṣẹlẹ si wọn.

Mba ni ohun to jẹ ko rọrun fawọn ajinigbe ọhun ni pe awọn ọlọpaa naa ko wọṣọ nigba ti wọn rin irin-ajo ọhun, ati pe mẹsan-an pere ni wọn, ki i ṣe mejila gẹgẹ bi awọn ileeṣẹ iroyin kan ti ṣe kede ẹ tẹlẹ.

Leave a Reply