Wọn ti ri mẹrinlelaaadọfa mu ninu awọn ẹlẹwọn to sa ni Kogi

Faith Adebọla

O jọ pe arọwa ti Minisita fọrọ abẹle, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ṣe fawọn ojilerugba (240) ẹlẹwọn ti wọn sa lọ lọgba ẹwọn Kogi lọjọ Aiku, Sannde to kọja, wọ awọn eeyan naa leti, pẹlu bijọba ṣe lawọn ti ri mẹrinlelaaadọfa mu ninu wọn pada, wọn si ti n ṣẹwọn wọn lọ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ẹlẹwọn nilẹ wa (NCoS), Ọgbẹni Francis Enobore, lo sọrọ yii di mimọ niluu Abuja lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, ninu atẹjade kan to fi lede lori ọrọ naa.

O ni ọpọ lara awọn ẹlẹwọn to jakun lọgba ẹwọn MSCC (Medium Security Custodial Centre) to wa niluu Kabba, nipinlẹ Kogi, lo fẹsẹ ara wọn rin pada wa, ti wọn si jọwọ ara wọn fawọn agbofinro, ṣugbọn awọn agbofinro lọọ fi pampẹ ofin gbe awọn mi-in lara wọn ni, nibi ti wọn sa pamọ si.

Atẹjade naa sọ pe “Ọga agba ileeṣẹ ẹlẹwọn, Ọgbẹni Haliru Nababa, lo ṣaaju awọn ikọ agbofinro ti wọn lọ lati ilu kan si omi-in, ti wọn n wa awọn ẹlẹwọn to jakun naa kiri, bakan naa ni wọn ti ro aabo yika ọgba ẹwọn naa lagbara si i.”

O sọ siwaju pe Ọgbẹni Nababa gboṣuba fawọn ileeṣẹ agbofinro ti wọn fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ ẹlẹwọn lati wa awọn ẹlẹwọn naa ri, ti wọn si da wọn pada.

Bakan naa lo rọ awọn ẹlẹwọn to ku lati jade nibikibi ti wọn fara sin si, tori ẹgbẹrun Saamu wọn ko le ribi kan sa m’Ọlọrun lọwọ, gbogbo orukọ, fọto ati akọsilẹ to peye nipa wọn lawọn yoo lo lati fi wa wọn lawari.

 

Leave a Reply