Wọn ti ri oku akẹkọọ Mount Carmel ti agbara ojo gbe lọ n’Ikarẹ Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Wọn ti ri oku akẹkọọ ileewe girama Mount Carmel, n’Ikarẹ Akoko, ti agbara ojo gbe lọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja, Motunrayọ John, nibi to ha si lẹyin ọjọ kẹrin.

ALAROYE gbọ pe oku Motunrayọ ni wọn ri nibi ti agbara ojo wọ ọ ju si lẹyin ile-itura kan niluu Igbe Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, Ọgbẹni Ade John to jẹ baba Motunrayọ juwe iku ọmọ rẹ bii kayeefi, ọfọ ati ibanujẹ ti ko ṣee ṣapejuwe fun oun ati iyawo rẹ, Abilekọ Adukẹ John.
Ọkunrin to yan isẹ ọkada ṣiṣe laayo ọhun ni ọmọ bibi ilu Ibọrọpa Akoko loun, o ni lati ibẹ lọmọ oun si ti n waa kawe ni Ikarẹ Akoko.
O ni igba Naira (#200) loun fun Motunrayọ laaarọ ọjọ iṣẹlẹ naa pe ko fi wọkọ pada sile ti oun ko ba raaye waa gbe e.
John ni bii ala lọrọ iku ọmọ oun ṣi n jọ loju oun lọwọ lọwọ, nitori pe iroyin naa ba oun lojiji pupọ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: