Wọn ti ri oku Fẹmi Oṣibọna to ni ile alaja mọkanlelogun to da wo n’Ikoyi

Jọkẹ Amọri

Ọkunrin to ni ileeṣẹ kan ti wọn n pe ni Fourscore, ti wọn loun lo ni ile alaja mọkanlelogun to da wo ni Mọnde, ọjọ Aje, ọsẹ yii, ni wọn ti ri oku rẹ ninu awoku ile ọhun nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, (The National Emergency Management Agency), lo sọ eleyii di mimọ nigba ti wọn ṣawari oku ọkunrin naa lasiko ti wọn n wo abẹ awoku ile ọhun lati ko awọn eeyan to wa nibẹ jade.

Latigba tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ lawọn kan ti n sọ pe o ṣee ṣe ki ọkunrin to nileeṣẹ naa wa nibẹ, nitori mọto rẹ wa lagbegbe ile ọhun lasiko iṣẹlẹ yii. Ṣugbọn awọn kan n sọ pe ko si nibẹ.

Awuyewuye yii ti dopin pẹlu bi ileeṣẹ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ṣe gbe oku ọkunrin naa jade.

Awọn eeyan naa ko duro, wọn ṣi n wọ abẹ akọku ile naa lati le yọ awọn yooku. Oku mẹrindinlogoji ni ALAROYE gbọ pe wọn ti gbe jade, ninu eyi ti ọkunrin mẹtalelogun ati obinrin mẹta wa.

Leave a Reply