Wọn ti sin Ọlatunji, alaga kansu Eti-Ọsa, to ku lojiji

Faith Adebọla, Eko

Tẹkun tomije lawọn mọlẹbi, ọrẹ, oṣiṣẹ kansu atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC fi pesẹ sibi eto isinku Oloogbe Alaaji Rafiu Ọlọrunfunmi Ọlatunji, alaga kansu onidagbasoke Eti-Ọsa to ku lojiji, loru mọju ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii.

Ile rẹ to wa lagbegbe Ṣangotẹdo, l’Ajah, ipinlẹ Eko, ni wọn ti ṣadura ikẹyin fun oloogbe ọhun laaarọ ọjọ Iṣẹgun, awọn alaafaa ni wọn waa dari eto isinku naa, ti wọn si sin in ni ilana ẹsin Musulumi.

Niṣe lawọn eeyan n wa ẹkun mu bii omi bi eto isinku naa ṣe n lọ lọwọ latari bi iku Oloogbe Ọlatunji ṣe ba wọn lojiji to. Wọn lọkunrin naa ni wọn kede pe o jawe olubori ninu eto idibo abẹlẹ APC lati yan ọmọ oye fun ipo alaga kansu ọhun, ireti si wa pe yoo lo saa keji nipo ọhun ti ko ba si iku to yọwọ ẹ lawo yii.

Wọn lọkunrin naa ko ṣaisan gidi kan, yatọ si bo ṣe sọ fawọn mọlẹbi ati amugbalẹgbẹẹ rẹ lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, lẹyin igbokegbodo ọjọ naa pe o fẹẹ rẹ oun diẹ, oun maa tete lọọ fara lelẹ lati sinmi, ṣugbọn ori isinmi naa lọlọjọ de ba a.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ẹgbẹ APC nipinlẹ Eko fi lede lori iṣẹlẹ ọhun, Ọgbẹni Ṣẹyẹ Ọladapọ sọ pe iyalẹnu gbaa niku ọkunrin naa jẹ fun ẹgbẹ APC.

O lawọn ba awọn mọlẹbi, oṣiṣẹ kansu ati ẹgbẹ APC kẹdun fun ipapoda to ṣẹlẹ yii, o ni ọmọ ẹgbẹ rere ni alaga ọhun nigba aye rẹ. O ṣapejuwe adanu yii bii ohun to nira lati mu mọra, o si ṣadura ki Ọlọrun tẹ ẹ safẹfẹ rere.

Bakan naa ni Alaga ijọba ibilẹ Eti-Ọsa, Ọnarebu Saheed Bankọle, daro oloogbe ẹlẹgbẹ rẹ yii, o ni adanu nla lo jẹ.

Ọgọọrọ lo kọminu si iku airoti to lu Ọnarebu Ọlatunju pa yii. Eyi ko ṣẹyin bi awuyewuye ṣe waye lẹyin abajade eto idibo abẹle sipo alaga ijọba ibilẹ lẹgbẹ APC, to waye laipẹ yii. Wọn ni bi eto idibo abẹle naa ṣe lọ ko tẹ ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ atawọn ti wọn jọ dije lọrun, eyi si mu ọpọ ikunsinu ati ifapajanu wa laarin ẹgbẹ ọhun.

Leave a Reply