Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Wọn ti kede iku adajọfẹyinti ile-ẹjọ giga ilẹ wa nni, Onidaajọ Bọlarinwa Adegoke Babalakin.
Inu ile rẹ niluu Gbọngan, nijọba ibilẹ Ayedaade, nipinlẹ Ọṣun, la gbọ pe baba yii dakẹ si lọjọ Abamẹta, Satide ọsẹ to kọja yii.
Ẹni ọdun mẹrindinlọgọrun-un ni, irọlẹ ọjọ Abamẹta naa ni wọn ti sinku rẹ nilana ẹsin Musulumi.