Wọn ti sinku Agboọla, agbẹ aladaa-nla ti awọn ajinigbe yinbọn pa n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ọsẹ meji ti awọn ajinigbe yinbọn pa a, wọn ti sinku Oluwọle Agboọla, agbẹ aladaa-nla ti awọn olubi ẹda ran lọ sọrun apandodo.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2020 yii, lawọn gende ọkunrin mẹfa kan ti wọn mura bii ọmọ ogun orileede yii ya wọnu oko baba naa to wa lọna Abule Nagbede, lagbegbe Mọniya, n’Ibadan, ti wọn si fipa mu un wọ inu igbo lọ niṣeju awọn oṣiṣẹ ẹ.

Ni nnkan bii ọjọ mẹwaa lẹyin naa, lọjọ kejila, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii, ni wọn ri oku ẹ ninu igbo, nibi kan ti ko jinna pupọ si inu oko ẹ ti wọn ti ji i gbe.

Bẹẹ, awọn ajinigbe ọhun ti ṣeleri fawọn ẹbi Agboọla pe awọn maa fi ẹni wọn silẹ bi wọn ba le san miliọnu meji Naira (₦2m). Ṣugbọn lẹyin ti wọn gbowo ọhun lọwọ wọn tan ni wọn papa yinbọn pa ọkunrin to kẹkọọ gboye giga ni Fasiti Ibadan (UI) yii.

Lọsan-an ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, ni wọn sinku ẹ nilana ti onigbagbọ.

Ṣaaju, iyẹn lọjọ Ẹtì, Furaidee, to koja, ni wọn ṣe isin ẹyẹ ikẹyin fun un nileejọsin New Convenant Church, to wa laduugbo Jericho, n’Ibadan.

Ẹni ọdun mejidinlaaadọta l’Ọgbẹni Oluwole nigba ti awọn olubi ẹda yinbọn pa a. Iyawo kan, Abilekọ Funmi Ọnadepo-Agboọla, pẹlu ọmọ mẹta ti gbogbo won jẹ ọkunrin loloogbe náà fi saye wọ kaa ilẹ lọ.

 

Leave a Reply