Wọn ti sinku Babatunde, akẹkọọ UNIOSUN to binu pa ara ẹ

Florence Babaṣọla

Ninu ẹkun, ibanujẹ ati aro ni wọn sinku Juba Babatunde Philips, akẹkọọ ileewe UNIOSUN to gbe majele jẹ lọjọ Tusidee to kọja yii.

Itẹ-oku to jẹ ti ijọ First Baptist Church, lagbegbe Sango, niluu Ikire, nijọba ibilẹ Irewọle, nipinlẹ Ọṣun, ni wọn sin oku ọmọdekunrin naa si.

Babatunde, ẹni to wa nipele akọkọ ni ẹka ti wọn ti n kọ nipa ere ori-itage nileewe naa la sọ fun yin pe o gbe majele (snippers) jẹ nirọlẹ ọjọ naa.

Nigba ti awọn ọrẹ rẹ fi maa denu yaara rẹ lọjọ naa, oku rẹ ni wọn ba, wọn si lọọ fi iṣẹlẹ naa to olori ẹṣọ aabo ileewe naa leti, latibẹ si lawọn ọlọpaa ti gbọ.

Wọn gbe Babatunde lọ sileewosan Catholic, niluu Apomu, nibẹ ni wọn si ti sọ fun wọn pe o ti jade laye.

Alukoro ileewe naa, Adesọji Ademọla, ṣalaye pe awọn obi Babatunde ni wọn lọọ gba oku naa nileewosan to wa, ti wọn si sin in ni itẹ-oku ọhun.

Leave a Reply