Wọn ti sinku dẹrẹba kọmiṣanna Ekiti tawọn ajinigbe yinbọn pa 

 Taofeeq Surdiq, Ado-Ekiti

Pẹlu omije loju lawọn mọlebi fin sinku awakọ Kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Ibrahim Olabọde, ti awọn ajinigbe yinbọn pa loju ọna Iṣan-Ekiti si Iludun, lopin ọsẹ to kọja yii.

Lakooko ti wọn n sinku ọmọkunrin naa, niṣe ni ẹkun ati omije gba oju awọn mọlẹbi rẹ atawọn eeyan ilu yii kan.

Dẹrẹba naa, to jẹ ọmọ ọdun mejilelogun, ti orukọ rẹ n jẹ Idowu Oguntuaṣe, ni awọn ajinigbe ti wọn ko ti i mọ yinbọn pa lakooko ti oun ati awọn mẹrin miran ti wọn jẹ oṣiṣẹ ijọba n lọ ni oju ọna Iṣan-Ekitim si Iludun, nijọba ibilẹ Ilejemeje.

Awọn mẹrin naa ni awọn ajinigbe ọhun ko wọ’nu igbo lọ ni kete ti wọn yinbọn pa dẹrẹba naa.

Oloogbe naa lawọn ajinigbe da duro ni ojuko kan ti ko dara loju ọna yii, ni kete ti wọn kuro niluu Iludun-Ekiti, ti wọn si kọju si ilu Eda-Ile.

Awọn agbebọn naa ti ẹnikan ko ti i mọ ni wọn f’ara pamọ si ibi kan ti ko dara loju ọna naa, ti wọn si da ọkọ to jẹ tikKọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ yii duro, ṣugbọn dẹrẹba ọkọ naa ko duro, ni wọn ba yinbọn pa a. Ṣugbọn lẹyin ti wọn yinbọn pa awakọ naa ni wọn ko awọn yooku wọ inu igbo lọ.

Ẹnikan ni Iludun-Ekiti sọ pe wọn ti sinku dẹrẹba naa pẹ̀u ẹdun ọkan sile awọn mọlẹbi rẹ n’Iludun -Ekiti, lopin ọsẹ to koja yii. Bẹẹ lawọn ọlọpaa sọ pe wọn ti gba iyọnda awọn yooku ti wọn ko lakooko ijinigbe naa.

Ninu ọrọ rẹ lori iṣẹlẹ ọhun, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe ọlọpaa ti gba awọn ti wọn ji ko naa silẹ lọwọ awọn ajinigbe lai fara pa, ti wọn si ti darapọ mọ awọn mọlẹbi wọn.

Abutu fi kun un pe akitiyan ti n lọ lọwọ laarin awọn agbofinro ipinlẹ naa lati ri awọn ajinigbe ọhun ko, pẹlu bi wọn ti ṣe da awọn ọlọpaa si gbogbo inu igbo to wa ni agbegbe ọhun.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, aṣofin to n ṣoju ìjọba ibilẹ Ilejemeje, nileegbimọ aṣofin ìpínlẹ̀ Ekiti, Ọmọọba-binrin, Iyabọ Fakunle-Okiẹmẹn, ṣalaye pe iṣẹlẹ ijinigbe ti n waye leralera nijọba ibilẹ naa.

Olori ileegbimọ aṣofin Ekiti, Ọgbẹni Adeoye Aribasoye, atawọn aṣofin yooku kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi awakọ naa.  Bakan naa ni wọn tun kẹdun pẹlu awọn eeyan ijọba ibilẹ Ilejemeje lori iṣẹlẹ ọhun.

Wọn waa ke si awọn agbofinro l’Ekiti, pe ki wọn tubọ jawe sobi idaabobo ẹmi ati dukia awọn eeyan ipinlẹ naa.

Leave a Reply