Faith Adebọla
Pẹlu iyalẹnu ati ẹdun ọkan gidi ni wọn sinku ọkan lara awọn olukọ Fasiti Ladoke Akintọla, LAUTECH, Ọjọgbọn Ọlajire Abass, to ku lojiji lọjọ Ẹti, Furaidee yii, lasiko to n kirun Jimọ ọjọ naa.
Ọsan ọjọ Abamẹta ni wọn sinku ọkunrin naa tẹkun-tomije si ile rẹ niluu Ibadan, nilana ẹsin Musulumi.
Ba a ṣe gbọ, wọn ni ko si aisan kan to n ṣe oloogbe ẹni ọdun mọkandinlọgọta naa tẹlẹ, bẹẹ ni ko si akọsilẹ ailera abẹnu kan nipa rẹ ju pe o ṣadeede ṣubu lulẹ lojiji nigba to n kirun Jimọ lọwọ, ti wọn si gbe e digbadigba lọ sileewosan ijọba to wa niluu Ogbomọṣọ, ṣugbọn ọkunrin naa papa dagbere faye.
Ọpọ eeyan, titi kan awọn alaṣẹ Fasiti Ladoke Akintọla University of Technology, niroyin iku ojiji yii kọ lominu. Alukoro ileewe naa, Ọgbẹni Lekan Fadeyi, sọ pe ‘agbọ-sọgba-nu ni iku Oloogbe Abass Abiọla Ọlajire jẹ fun wa ni fasiti yii, ọkan ninu awọn ọjọgbọn ta a fẹmi tẹ nidii iṣẹ iwadii ni, paapaa lori ọrọ to ba jẹ mọ imọ nipa apopọ kẹmika loriṣiiriṣii.’
Adele Ọga agba fasiti ọhun, Ọjọgbọn Mọjeed Ọlaide Liasu sọ pe iku olukọ ti aye n wari fun yii ya oun lẹnu gidigidi, o ni irawọ nla kan lo ja lulẹ lojiji nileewe naa, tori asiko tawọn nilo imọ ati iṣẹ ọkunrin naa lo jade laye yii.
Ọlajide to gba awọọdu olukọ to mọọyan an kọ ju lọ nileewe naa lọdun 1994 ti kopa ninu ọpọ iṣẹ iwadii ijinlẹ, titi de ilu oyinbo si ni awọn iṣẹ iwadii rẹ fi wulo titi di ba a ṣe n sọ yii.