Wọn ti sọ ina si teṣan ọlọpaa l’Oṣodi, l’Ekoo

Faith Adebọla

Eefin ina nla ti goke ni teṣan ọlọpaa Makinde, to wa l’Oshodi, nipinlẹ Eko, awọn ọdọ ti inu n bi ni wọn sọ ina si teṣan ọlọpaa naa laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ninu iwọde to gba gbogbo ipinlẹ naa kan.

Ohun ti a gbọ ni pe awọn ọdọ agbegbe naa rọ lọ si teṣan ọhun lati fi ẹhonu han ta ko bawọn ṣọja kan ṣe pa awọn ọdọ to n ṣe iwọde lode SARS, lagbegbe Too geeti, Lẹkki, lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Wọn ni DPO teṣan naa rọ awọn ọdọ yii lati kuro lẹnu geeti teṣan ọhun, nigba ti arọwa rẹ ko wọ wọn leti lo ba yinbọ soke. Bo tilẹ jẹ pe ibọn naa ko ba ẹnikẹni, niṣe lawọn ọdọ naa tubọ fa ibinu yọ, wọn si da epo bẹtiroolu si teṣan naa, ni wọn ba dana sun un.

Obitibiti ero lo wa niwaju teṣan naa ti wọn n woran bi ile naa ṣe n jona.

Leave a Reply