Wọn ti tu Imaamu agba ti wọn ji gbe ni Ùsò silẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Imaamu agba ti ilu Ùsò, n’ijọba ibilẹ Ọwọ, Alaaji Ibrahim Bọdunde Oyinlade, lori ti ko yọ lọwọ awọn janduku to ji i gbe. Ibi kan loju ọna marosẹ Akurẹ si Ọwọ ni wọn lọọ ja baba agbalagba naa si lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa, nibi tawọn eeyan kan ti ṣalabaapade rẹ lẹyin ọjọ keji ti wọn ti gbe e sa lọ.

Ohun ta a gbọ lati ẹnu iya agbalagba kan to jẹ ọkan lara ẹbi Imaamu ọhun ni pe awọn ajinigbe ọhun ti kọkọ pe awọn, ti wọn si beere fun miliọnu marun-un Naira ki wọn too le tu baba naa silẹ.

A ko ti i rẹni sọ fun wa boya wọn pada gbowo ọhun lọwọ awọn ẹbi rẹ tabi wọn ko ri i gba ki wọn too tu ojiṣẹ Ọlọrun naa silẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Imaamu agba Mọsalasi Ùsò, lawọn ajinigbe ọhun ji gbe ninu oko rẹ lọsan-an ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹfa.

Leave a Reply