Wọn ti tun dana sun agọ ọlọpaa Layẹni, l’Ajegunlẹ

Faith Adebọla

O da bii pe agọ ọlọpaa ni awọn ọmọọta to n fa wahala doju kọ bayii pẹlu bi wọn ṣe tun dana sun agọ ọlọpaa to wa ni Layẹni, ni agbegbe Ajegunlẹ, beẹ ni wọn tun kọ lu awọn ọlọpaa ni teṣan Pako.

Ẹni to fi iroyin naa to ALAROYE leti ṣalaye pe ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni wọn kọ lu agọ ọlọpaa naa, lẹyin ti wọn jo agọ ọlọpaa to wa ni Orile.

Bakan naa ni wọn ti kọ lu agọ ọlọpaa to wa ni Pako, ti wọn si ṣe awọn eeyan leṣe nibe naa.

Teṣan ọlọpaa to wa ni Orile Iganmu ni wọn kọkọ dana sun ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ ọjọ Iṣẹgun. Ohun to fa wahala yii ni ẹsun ti wọn fi kan ọlọpaa kan ni teṣan naa pe oun lo yinbọn pa ọkan lara awọn ọdọ to n ṣewọde tako SARS lowurọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, yii.

Abilekọ Modupẹ to ba akọroyin sọrọ lori atẹ ayelujara sọ pe oun wa nibi iṣẹlẹ naa, o ni ki i ṣe awọn ọdọ to n fẹhonu han ta ko SARS ni wọn dana sun agọ ọlọpaa naa, o ni awọn araalu atawọn janduku ni wọn n binu lori ọdọkunrin kan ta a ko ti i mọ orukọ rẹ ti wọn ni ọlọpaa kan ni tẹsan naa lo yinbọn pa a ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ owurọ yii.

Leave a Reply