Wọn ti tun ji ọba alaye mi-in gbe l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Awọn agbebọn kan ti ji ọba alaye kan, Ọba Adeniran Ọshọ, to jẹ ọba ilu Ẹda-Ekiti, nijọba ibilẹ Ẹda-Oniyọ nipinle naa.

Kabiyesi to jẹ oṣiṣẹ-fẹyinti lẹnu iṣẹ ologun ni wọn ji gbe loju iyawo rẹ lori ilẹ oko wọn to wa niluu Ẹda-Ile, ni kutukutu aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, yii.

Iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ nigba to pe oṣu meji ti awọn ajinigbe  kan ti wọn ko ti i mọ ji Ọba David Oyewumi tilu Ilemeshọ-Ekiti, nijọba ibilẹ Ọyẹ gbe.

Ẹnikan ti ko fẹ ka darukọ oun to ba ALAROYE sọrọ, sọ pe ọba alaye yii ati iyawo rẹ ji lọ soko ni kutukutu owurọ ọjọ Abamẹta, ṣugbọn bi wọn ṣe n dari pada bọ ni wọn pade awọn ajinigbe yii, ni wọn ba ko awọn mejeeji papọ. A gbọ pe kabiyesi yii lo rawọ ẹbẹ sawọn ajinigbe yii pẹlu idọbalẹ pe ki wọn fi iyawo oun silẹ, ti wọn si sọ fun iyawo yii pe ko gbọdọ sọrọ pe awọn ajinigbe ti gbe ọkọ oun, afi to ba pe ọjọ mẹta ti wọn ti ji i gbe.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Oludari ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ naa, Ọgagun Joe Kọmọlafẹ, sọ pe loootọ ni ijinigbe naa ṣẹlẹ, ṣugbọn awọn ọmọ ogun oun ati awọn oṣiṣẹ alaabo miiran pẹlu awọn ọdẹ ibilẹ ti wa ninu igbo ni gbogbo agbegbe naa, ti wọn si n wa awọn ajinigbe naa.

O ṣeleri pe awọn yoo gba kabiyesi naa jade pẹlu ayọ ati alaafia lai fara pa. O rawọ ẹbẹ sawọn araalu, ni pataki ju lọ, awọn to wa ni agbegbe naa pe ki wọn ma bẹru lati ta awọn lolobo, ati lati fun wọn ni alaye to le ran wọn lọwọ lati tete ri kabiyesi naa gba jade ni kia kia.

Leave a Reply