Wọn ti yan Yaya Bello gẹgẹ bii alaga igbimọ ti yoo ṣeto idibo abẹle APC nipinlẹ Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 
Gomina ipinlẹ Kogi, Alaaji Yaya Bello, ni wọn ti kede orukọ rẹ gẹgẹ bii alaga igbimọ to fẹẹ mojuto eto ibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC ti yoo waye lọjọ Aje, Mọnde ọsẹ to n bọ.
Ikede yii lo waye lati ẹnu igbakeji akọwe ipolongo ẹgbẹ APC lorilẹ-ede yii, Yẹkini Nabẹna lonii tii ṣe Ọjọbọ, Tọsidee.
Aago mẹta ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun osu yii, lo ni alaga afunṣọ ẹgbẹ naa, Gomina Mai Mala Buni, yoo ṣagbekalẹ igbimọ ẹlẹni mẹsan-an ọhun ni olu ile ẹgbẹ wọn l’Abuja.

Leave a Reply