Faith Adebọla
Oludamọran pataki si Aarẹ Goodluck Jonathan lori ọrọ oṣelu, Ọgbẹni Ahmed Gulak, ti doloogbe, awọn agbebọn kan la gbọ pe wọn yinbọn pa a laaarọ ọjọ Aiku, Sande yii.
Ilu Owerri, nipinlẹ Imo, ni iṣẹlẹ buruku naa ti waye, wọn loloogbe naa n dari pada siluu Abuja lẹyin ipade oṣelu kan to lọọ ṣe niluu Owerri ni, ko too pade iku ojiji yii.
Agba-ọjẹ ẹgbẹ oṣelu APC ni Gulak, bo tilẹ jẹ pe lẹyin iṣakoso Jonathan lo kuro lẹgbẹ oṣelu PDP.