Wọn tun n bakan bọ: Wọn ni ọga ọlọpaa pata ni yoo maa dari eto Amọtẹkun o

O da bii pe gbogbo eto yoowu ti awọn gomina ilẹ Yoruba ba ṣe lori ikọ Amọtẹkun ko ni i ṣiṣẹ bi ki i baa ṣe pe wọn tẹle ilana ti ọga awọn ọlọpaa patapta ba la kalẹ fun wọn. Ileeṣẹ aarẹ lo sọ bẹẹ, lati ọdọ ọkan ninu awọn agbẹnusọ ibẹ, Garba Shehu.

Ọkunrin naa ni eto ti wa nilẹ ti ijọba Buhari ṣe fun awọn ọlọpaa ibilẹ, labẹ eto awọn ọlọpaa ibilẹ yii si ni ikọ bii ti awọn Amotẹkun bọ si, ohun yoowu ti ọga olopaa pata ba si ti la kalẹ fun wọn ni wọn yoo tẹ le, ẹnikẹni ti ko ba si tẹ le e yoo da ara rẹ lẹbi. Bẹẹ ni Garba wi.

Bi ẹ ba ranti, lati igba tawọn ijọba ilẹ Yoruba gbogbo ti ronu Amọtẹkkun ti wọn si ti gbe eto rẹ jade ni awọn eeyan ijọba apapọ ko fi taratara fẹ kinni ọhun, ohun to si i fa a ti wọn fi sare da ohun ti wọn pe ni ọlọpaa ibilẹ silẹ ree, ti wọn ni awọn gangan ni araalu nilo, ki iṣe awọn Amọtẹkun kankan. Ọsẹ to kọja yii ni Buhari gbe owo bii bilionu mẹtala kalẹ pe ki wọn fi bẹrẹ eto agbekalẹ awọn olọpaa ibilẹ yii, to si jẹ awọn gomina ni yoo pada maa sanwo oṣu fawọn ti wọn ba gba siṣẹ ọhun.

Bi Amọtẹkun yoo ṣe ṣiṣẹ labẹ eto ọlọpaa ibilẹ ati ọga ọlọpaa patapata lẹni kan ko ti i le sọ.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Tori pe wọn yinbọn paayan meji, afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meje dero ahamọ l’Abẹokuta

Gbenga Amos, Abẹokuta Lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un yii, lawọn gende mẹrin …

2 comments

  1. O but jai wipe ijoba apapo ko gboju kuro ninu eto ti Yoruba gbe kale fun eto aabo ara won, o ga o. Yoruba ko ni gba rara.

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: