Wọn tun paayan rẹpẹtẹ lasiko ija awọn ọmọ iṣọta n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

O kere tan, eeyan mẹfa la gbọ pe wọn j’Ọlọrun nipe nigboro Ibadan, nigba tawọn tọọgi adugbo Popo-Yeọsa, Abẹbi ati Nalende, fija pẹẹta.

Iroyin mi-in ta a gbọ ni pe awọn to ku ninu iṣẹlẹ yii ko din ni mejila.

Ija ti ko sẹni to ti i mọ ohun to ṣokunfa rẹ yii yatọ sawọn to n ja a, ni wọn lo bẹrẹ nirọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja yii, to si tẹsiwaju di aarọ ọjọ keji ti i ṣe Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja.

Rogbodiyan to gb’ẹmi eeyan bii mẹfa yii lo waye lọjọ keji ti awọn ẹgbẹ onimọto paayan meji ninu ija to waye laarin ẹgbe awọn awakọ pẹlu awọn to n ta foonu laduugbo Iwo Road. Ọkan ninu awọn to ba iṣẹlẹ ọhun rin lọkunrin kan to kẹkọọ gboye ni Fasiti Lead City, n’Ibadan, Rahman Azeez.

Olugbe adugbo Opopo-Yeọsa kan fìdí ẹ mulẹ pe, “Nigba ti a n mura lati kirun Alaasari lọjọ Wẹsidee ni rogbodiyan yẹn bẹ silẹ nigba ti awọn tọọgi ṣigun de lati Nalende pẹlu ibọn ati ada, ti awọn ti Oopo-Yeọsa nibi naa si koju wọn.

“Eeyan marun-un lawọn ara Nalende yinbọn pa, awọn ọmọ Oopo naa pa ọkan ninu wọn.

“Lọjọ Wẹsidee ni wọn kọkọ bẹrẹ ija yẹn ki awọn ara Nalende too pada wa lọjọ Tọsidee, to fi di pe wọn paayan nipakupa.”

Ṣugbọn ẹlomi-in to sọrọ lori iṣẹlẹ yii sọ pe apapọ eeyan ti wọn yinbọn pa ninu laasigbo ọhun ko din ni mejila, nitori eeyan meje lawọn ara Nalende pa ni Oopo-Yeọsa, nigba tawọn yẹn naa pa marun-un dipo ninu wọn.

Titi ta a fi pari akojọ iroyin yii lawọn olugbe awọn agbegbe naa ṣi wa ninu ipaya nitori wọn ko mọ boya ija naa tun le tẹsiwaju nigbakuugba.

Akitiyan lati fidi iroyin yii mulẹ lọdọ awọn agbofinro ko seso rere pẹlu bi agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, ko ṣe gbe ipe akọroyin wa titi ta a fi pari iroyin yii.

Leave a Reply