Wọn tun ti ji awọn arinrin-ajo meji gbe l’Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Iṣẹlẹ ijinigbe to n waye lagbegbe Akoko tun gbọna mi-in yọ pẹlu bi wọn tun ṣe ji obinrin oniṣowo kanAgnes Akọgun, ati awakọ rẹOkio, gbe lalẹ ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii. 

Obinrin oniṣowo ọhun ati awakọ rẹ la gbọ pe wọn ji gbe laarin ilu Ugbe, nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko, si Uba-Ọka nijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Akoko. 

Awọn ọja aṣọ ti obinrin naa n ta ni wọn lo n ko lọ si Uba-Ọka, lasiko ti awọn ajinigbe ọhun da wọn lọna, ti wọn si ko wọn wọnu igbo lọ. 

Ni kete tawọn eeyan ti gbọ nipa iṣẹlẹ yii ni wọn lawọn ọdẹ, awọn fijilante atawọn ọlọpaa Ọka Akoko ti n wa gbogbo inu aginju to wa lagbegbe naa boya wọn le ri wọn gba pada. 

Awọn ajinigbe ọhun la gbọ pe wọn ko ti i kan si ẹnikẹni ninu awọn ẹbi awọn ti wọn ji gbe naa ni gbogbo asiko ta a fi n ko iroyin yii jọ lọwọ.

Leave a Reply