Wọn tun ti ji awọn ọmọ fasiti rẹpẹtẹ gbe ni Makurdi

Faith Adebọla

Kaka k’ewe agbọ dẹ, koko lo n le si i lọrọ awọn janduku agbebọn pẹlu bi wọn ṣe ṣiju si awọn ileewe Fasiti ilẹ wa bayii, awọn apamọlẹkun ẹda naa ti tun lọọ ji awọn ọmọ fasiti FUAM (Federal University of Agriculture) gbe, niluu Makurdi, ipinlẹ Benue.

Oru ọjọ Aiku, Sannde, mọju ọjọ Aje, Mọnde yii, la gbọ pe awọn agbebọn naa ya bo ọgba fasiti ọhun, lasiko tawọn akẹkọọ ti wọn gbe inu kampọọsi ileewe ṣi n sun lọwọ, ni wọn ba ṣina ibọn bolẹ, wọn si ko ọpọ awọn ọmọleewe naa wọgbo lọ.

Alamoojuto eto iroyin ati alukoro fasiti naa, Abilekọ Rosemary Waku, kede ninu atẹjade kan lọjọ Aje pe: “Awọn agbebọn kan ti waa fibọn ka awọn akẹkọọ Fasiti FUAM mọle lalẹ ana (Sannde) mọju aarọ yii (Mọnde), ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii. A o ti i mọye awọn akẹkọọ naa. A ti lọọ fiṣẹlẹ yii to awọn ọlọpaa, ati ẹka agbofinro gbogbo leti. A o ti gbọ nnkan kan latọdọ awọn to ji wọn gbe, a o si ti i mọ inu igbo ti wọn ko wọn lọ. A bẹ ijọba lati ran wa lọwọ.”

B’ALAROYE ṣe gbọ, ọpọ awọn akẹkọọ to ṣẹku ninu ọgba ileewe naa ti sa kuro nigba tilẹ mọ, inu ibẹrubojo lawọn eeyan agbegbe naa ṣi wa bayii. A gbọ pe ọpọ awọn obi ni wọn ti ya bo ileewe naa tọlọmọ si n wa ọmọ rẹ.8

Eyi ni igba keji laarin ọsẹ kan tiṣẹlẹ jiji awọn ọmọleewe fasiti maa waye. Alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii, lawọn agbebọn ji awọn ọmọleewe mẹtadinlogun gbe ni fasiti aladaani Greenfield University, niluu Kaduna, ti wọn si yinbọn pa mẹta danu ninu awọn akẹkọọ naa.

Titi dasiko yii, awọn ọmọleewe naa ṣi wa lakata awọn agbebọn ọhun.

Leave a Reply