Wọn tun ti ri ile mi-in ti wọn ti n ṣe òwò ọmọ tita ni Mowe

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Lẹyin ọjọ meji ti aṣiri ile ti wọn ti n ta awọn ọmọ ikoko tawọn ọmọbinrin ti ko ti i dagba ba bi ni Mowe tu, awọn ọlọpaa adugbo naa tun ti ri ile mi-in to jẹ owo ọmọ tita ni wọn n ṣe nibẹ ni Mowe kan naa.

Opopona Lagos, Adesan, ni Mowe, ni ile ti wọn ti n fi awọn ọmọbinrin keekeeke ṣowo ibasun, ti wọn si n ta ọmọ ti wọn ba bi yii wà.

Awọn araadugbo ni wọn sọ fọlọpaa pe ara n fu awọn si ile naa, nitori o fẹrẹ ma si ẹni kan ninu àwọn obinrin wẹwẹ to n gbebẹ ti ko loyun.

Wọn ni ko sẹni ti i rọmọ lẹyin ejo si lọrọ wọn, ko sẹni to n ri ọmọ ti wọn ba bi, wọn lo jọ pe wọn n lo awọn aboyún naa fun tita ọmọ ti wọn ba bi ni.

Nigba ti DPO Mowe, SP Marvis Jayeọla, atawọn eeyan ẹ debẹ ni wọn ri i pe bẹẹ lo ri loootọ.

Wọn ba oloyun kan ti ikun rẹ ti tóbi daadaa nibẹ, wọn si tun ri ọmọbinrin kan to ṣẹṣẹ bímọ ti wọn si ti ta ọmọ rẹ.

Wọn tun ri awọn obinrin meji mi-in pẹlu awọn ọmọde mẹrin. Ọkunrin kan naa wa nibẹ tawọn ọlọpaa mu, wọn ni gbogbo ẹri lo foju han pe iya to n ta awọn ọmọ ọlọmọ nibẹ lo n ṣíṣẹ fun, obinrin ti wọn n pe ni Florence Ogbonna to sa lọ lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, ni wọn lo tun mọ nipa ile keji yii naa.

 

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ pe ijọba ti mu Florence ọhun ri lori ẹsun tita awọn ọmọ ọlọmọ lẹyin to ba fi ipa sọ awọn ọmọdebinrin di iya ojiji tan.

Leave a Reply