Wọn wọ Ọnarebu Afọlabi lọ sile-ẹjọ lori ẹsun ibanilorukọ jẹ l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọkan lara awọn agba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Ọṣun, Oloye Moshood Oluawo, ti wọ ọmọ ile igbimọ aṣofin apapọ to n ṣoju awọn eeyan agbegbe Ifẹlodun/Boripẹ/Odo-Ọtin, Ọnarebu Rasheed Afọlabi, lọ si kootu lori ẹsun ibanilorukọ jẹ.

Ninu iwe ipẹjọ to ni nọmba HOS/33/2022 ni Oluawo ti n beere fun ẹẹdẹgbẹta miliọnu Naira (#500 million) gẹgẹ bii owo ‘gba ma binu.’

Gẹgẹ bi agbẹjọro Oluawo, Muhydeen Adeoye, ṣe kọ sinu iwe ipẹjọ naa, eleyii to gbe lọ siwaju ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun to wa niluu Oṣogbo, o ṣalaye pe ṣe ni awọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ ranṣẹ pe oun si ọfiisi wọn niluu Oṣogbo loṣu Kẹwaa, ọdun 2021.

O ni latari lẹta kan ti Afọlabi kọ si wọn ni wọn ṣe pe oun, o ni ṣe ni ọkunrin aṣofin naa sọ pe oun (Oluawo) loun wa nidii iṣẹlẹ bi awọn kan ṣe gbiyanju lati ṣeku pa oun loju-ọna Kogi si Lọkọja nigba ti oun n lọ si Abuja.

Olupẹjọ sọ siwaju pe Afọlabi tun pe oun ni agbanipa niwaju ajọ ọtẹlẹmuyẹ lọjọ naa, to si jẹ pe lẹyin ọpọlọpọ fitina ti wọn fi oju oun ri ni wọn too sọ pe gbogbo ẹsun naa ko nitumọ, ti ko si si otitọ kankan nibẹ, ti wọn si ni ki oun maa lọ lalaafia.

Oluawo fi kun ọrọ rẹ pe latigba tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ni nnkan ko ti lọ deede fun oun mọ nitori ṣe lawọn eeyan bẹrẹ si i sa fun oun, paapaa ju lọ, pẹlu bo ṣe jẹ pe oun n mura lati du aaye ti Afọlabi wa lọwọlọwọ.

O waa bẹbẹ pe ki ile-ẹjọ la ponpo owo to to miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta Naira mọ olujẹjọ lori, ki adajọ si paṣẹ pe ki o bẹbẹ ninu iwe iroyin ojoojumọ ilẹ wa mẹfa ọtọọtọ.

Amọ ṣa, Onidaajọ A. Onibokun ti fun olupẹjọ lanfaani lati lọọ lẹ iwe ipẹjọ naa mọ ọfiisi ipolongo ibo olujẹjọ to wa niluu Ikirun.

Leave a Reply