Wọn yan Adebayọ Shittu gẹgẹ bii adari iponlogo ibo aarẹ fun Tinubu

Ọlawale Ajao, Ibadan
Wọn ti yan minisita feto iroyin nilẹ yii tẹlẹ, Alhaji Adebayọ Shittu, gẹgẹ bii alakooso eto ipolongo ibo aarẹ fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti i ṣe oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu All Progresives Congress (APC).
Igbimọ ti yoo maa polongo ibo fun Tinubu ọhun ni wọn pe ni Asiwaju Tinubu Presidential Campaign Organisation (ATPCO).
Atẹjade to wa lati ọdọ igbimọ ATPCO fidi ẹ mulẹ pe lopin ọsẹ yii ni wọn fi lẹta iyansipo ọhun ranṣẹ si Alhaji Shittu, loju-ẹsẹ lo si ti tẹwọ gba ipo naa pẹlu ileri lati jiṣẹ ọhun gẹgẹ bi wọn ṣe ran an.
Wọn ni nitori ipa ribiribi ti Shittu ko nibi ipolongo ibo Aarẹ Muhammadu Buhari lọdun 2019 ati 2015 lo jẹ ki wọn yan an sipo naa.
“Ni bayii ti Aṣaaju wa, Bọla Tinubu, ti di oludije fun ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu wa, APC, ohun to ku bayii ni lati pa gbogbo ẹgbẹ keekeeke ti onikaluku wa ba ni ninu ẹgbẹ APC pọ, ki wọn si ko ara wọn jọ si idari ẹgbẹ tuntun yii, ka le wa ni iṣọkan lati le ṣaṣeyọri fun ẹgbẹ APC ati oludije wa”. Bẹẹ ni wọn ṣe sọ ninu atẹjade naa.
Nigba to n gba lati jiṣẹ ti wọn gbe le e lọwọ naa, minisita nigba kan ri yii ṣeleri pe gbogbo nnkan ti oun ni loun yoo lo fun ipolongo naa lati ri i pe ẹgbẹ APC ati Aṣiwaju Tinubu jawe olubori ninu idibo ọhun ti yoo waye lọdun 2023.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//eephaush.com/4/4998019
%d bloggers like this: