Wọn yinbọn pa adari ileeṣẹ ijọba ibilẹ l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Inu ibẹru nla lawọn eeyan adugbo Umesi, lagbegbe Igirigiri, niluu Ado-Ekiti, wa di asiko yii pẹlu bi awọn agbebọn kan ṣe pa ọkan lara awọn adari ileeṣẹ ijọba ibilẹ nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni David Jejelowo, sinu ile ẹ.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago kan oru ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii niṣẹlẹ naa waye, bẹẹ ni ko sẹni to mọ boya awọn adigunjale ni tabi awọn agbanipa.

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, sọ pe loootọ ni wọn yinbọn pa ọkunrin naa, inu yara ẹ gan-an ni wọn si ṣeku pa a si. O ni ko sẹni to mọ nnkan to ṣẹlẹ ki iṣẹlẹ naa too waye, eyi si ni afojusun iwadii ọlọpaa.

O ni, ‘‘Titi di asiko yii, a ko mọ idi ti wọn fi pa ọkunrin naa, bakan naa ni ko sẹni to mọ awọn to ṣiṣẹ ọhun, ṣugbọn nnkan ta a le fidi ẹ mulẹ ni pe wọn yinbọn pa a ni.’’

Abutu sọ ọ di mimọ pe wọn ti gbe oku oloogbe naa lọ si mọṣuari ileewosan ẹkọṣẹ Faisiti Ekiti (EKSUTH) to wa niluu Ado-Ekiti.

One thought on “Wọn yinbọn pa adari ileeṣẹ ijọba ibilẹ l’Ekiti

Leave a Reply