Wọn yinbọn pa eeyan mẹta, awọn mi-in tun fara gbọta lasiko atundi ibo ile-igbimọ aṣofin Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

 

Wahala nla ni atundi ibo to waye ni ẹkun idibo Ila-Oorun Ekiti kin-in-ni lati yan ẹlomi-in sipo aṣofin to ku da silẹ lọjọ Abamẹta, Satide to kọja, pẹlu bi wọn ṣe yinbọn pa eeyan mẹta, ti ọpọlọpọ si fara gbọta.

Ibo naa ni wọn di lẹyin ti aṣofin to n ṣoju ẹkun naa tẹlẹ, Ọnarebu Juwa Adegbuyi, dagbere faye lọsẹ diẹ sẹyin.

ALAROYE gbọ pe awọn mẹta ni wọn yinbọn pa nigba tawọn tọọgi ya bo Ibudo ibo keje, Wọọdu keje, niluu Omuo-Ekiti, bẹẹ ni ọlọpaa meji, oṣiṣẹ ajọ oju popo kan, agunbanirọ kan atawọn mi-in ti wọn fara pa balẹ sileewosan.

Mẹji ninu awọn to padanu ẹmi wọn ni Bọla Adebisi, ẹni aadọta ọdun, ati Tunde Ogunlẹyẹ toun jẹ ẹni ọdun marundinlogoji.

Bakan naa la gbọ pe wọn tun gbe apoti ibo ni Wọọdu kẹsan-an, ibudo idibo kẹjọ, niluu ọhun.

Nigba to n ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, Sẹnetọ Biọdun Olujimi to n ṣoju awọn eeyan Guusu Ekiti nile igbimọ aṣofin agba sọ pe diẹ lo ku ki wọn yinbọn pa oun lasiko rogbodiyan ọhun, awọn alatilẹyin ẹgbẹ People’s Democratic Party (PDP) lo si gbe oun sa kuro nibẹ.

Olujimi ni, ‘‘Pẹlu alaafia ni ibo yẹn bẹrẹ. Awọn adari APC (All Progressives Congress) gan-an wa si ibudo idibo yẹn, a dẹ ki ara wa. Nigba ti wọn lọ tan ni awọn tọọgi to duro lẹyin gbe ibọn jade, ti wọn si bẹrẹ si i yin in. Igba akọkọ ta a maa ri iru ẹ niyi. Wọn tiẹ tun gbe apoti ibo sa lọ.

‘’‘Ọkunrin kan ku nigba to fẹẹ gbiyanju lati sa lọ, bẹẹ ni wọn yinbọn lu ọlọpaa obinrin to duro ti apoti yẹn lori. Agunbanirọ kan ati alakooso ibo naa fara gbọta. Eeyan mẹjọ nibọn ba, awọn kan ti ku, awọn to ku wa lẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun nileewosan.

Olujimi waa fẹsun kan APC pe awọn gan-an ni wọn da rogbodiyan ọhun silẹ, ati pe wọn ko awọn tọọgi wọ ilu naa nitori ibo to waye ni wọọdu marun-un pere.

Ninu ọrọ tiẹ, Ọnarebu Fẹmi Bamiṣilẹ to jẹ ọmọ ilu naa, to si wa nile-igbimọ aṣoju-ṣofin lọwọlọwọ sọ pe iṣẹlẹ iyanu gbaa lọrọ ọhun, nitori ko si nnkan to yẹ ko fa itajẹsilẹ ninu idibo nilẹ yii.

Bamiṣilẹ, ọmọ ẹgbẹ APC, ni, ‘‘Ninu ibo ti ẹmi awọn eeyan ba ti bọ, iyẹn ki i ṣe dẹmokiresi mọ. APC gbaradi fun ibo yii ni gbogbo ọna, a dẹ beere fun atilẹyin awọn oludibo, bẹẹ ni a ko gbero lati pa ẹnikẹni. Mi o mọ bi iṣẹlẹ yii ṣe ṣẹlẹ, mi o si ro pe awọn ọmọ ẹgbẹ wa lo ṣe e. Pẹlu alaafia ni ibo yẹn bẹrẹ, ki lo waa ṣẹlẹ to fi di pe wọn n yinbọn ti wọn tun paayan?’’

Bakan naa ni Ọgbẹni Akinrinade Adeniran, oludije PDP ninu ibo ọhun, sọ pe ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja, tawọn kan ti fi ọta ibọn da batani si mọto oun, ti wọn si tun yinbọn si orule ile oun loun ti mọ pe wahala n bọ.

Ṣugbọn ninu alaye tiẹ, Alukoro ọlọpaa l’Ekiti, ASP Sunday Abutu, sọ pe eeyan mẹfa nibọn ba, ọlọpaa meji ati agunbanirọ kan si wa ninu wọn, bẹẹ ni wọn n gba itọju lọwọ ni General Hosipital to wa niluu Ikọle-Ekiti.

O waa ni Gomina Kayọde Fayẹmi ti kede pe gbogbo awọn to ba lọwọ ninu rogbodiyan naa lọwọ gbọdọ tẹ ki wọn le foju wina ofin.

Leave a Reply