Wọn yinbọn pa ọlọkada n’Ibadan, wọn tun gbe  ọkada ẹ lọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Kayeefi niku ọlọkada kan ṣi n jẹ fun gbogbo ara ipinlẹ Ọyọ, paapaa, awọn olugbe adugbo Akinyẹle, n’Ibadan, pẹlu bi wọn ṣe yinbọn pa ọkunrin naa, idi ti wọn si ṣe ran an lọ sọrun ko ti i ye ẹnikan

Laaarọ kutu ijẹta, iyẹn ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹsan-an, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii, niṣẹlẹ ọhun waye, nigba tawọn amookunṣika ẹda ọhun tẹnikẹni ko ti i mọ bayii da ọkunrin naa lọna loju ọna ti wọn n gba t’Ibadan lọ siluu Ọyọ nigba kan, ti wọn si ran an lọ sọrun apapandodo.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, niṣe lawọn olubi eeyan naa gbe ọkada ọkunrin naa sa lọ lẹyin ti wọn yinbọn pa a tan.

Olugbe adugbo ohun kan to ba akọroyin wa sọrọ lori iṣẹlẹ yii fidi ẹ mulẹ pe o fẹẹ jẹ ojoojumọ lawọn ole n ja maṣinni gba mọ awọn ọlọkada lọwọ lagbegbe yii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘Wọn pa ọkunrin kan si oju ọna Ibadan si Ọyọ lọjọ Sannde. A n fi akoko yii ke si ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lati wa nnkan ṣe si ọrọ awọn adigunjale yii nitori o fẹẹ jẹ pe ojoojumọ ni wọn n da awọn ọlọkada lọna lAkinyẹle”.

 

Leave a Reply