Wọn yinbọn pa sọrọsọrọ ori redio kan n’Ibadan

Awọn agbebọn kan ti awọn eeyan fura si pe o ṣee ṣe ko jẹ ayakila ti yinbọn pa gbajumọ sọrọsọrọ ori redio kan niluu Ibadan, Titus Badejọ, ti gbogbo eeyan mọ si Ejanla lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ to kọja yii.

ALAROYE gbọ pe lasiko to fẹẹ kuro ni ileegbafẹ kan to ti n ṣe faaji ni adugbo Oluyọle ni wọn ṣina ibọn fun un laarin awọn ti wọn jọ wa nibẹ, ti wọn si ri i pe o ku ki wọn too kuro nibẹ.

A gbọ pe lati nnkan bii aago mẹsan-an alẹ lo ti wa ni kilọọbu kan to wa ni Oluyọle Estate, nibi to ti n ṣe faaji pẹlu awọn eeyan kan. Ni nnkan bii aago mọkanla kọja ni wọn lo fi kilọọbu naa silẹ to n lọ sile.

Lojiji ni awọn agbebọn yii yọ si wọn, ti wọn si ni ki gbogbo awọn to wa nibẹ dojubolẹ. Ṣugbọn oun nikan ni awọn apani-jaye yii kọju ibọn si, ti wọn si ri i pe ẹmi bọ lara rẹ ki wọn too kuro nibẹ. Ohun to jẹ ki awọn eeyan fura pe o ṣee ṣe ko jẹ ayakila ni pe wọn ko gba nnkan kan lọwọ ọkunrin naa, bẹẹ ni wọn ko mu ohunkohun kuro lara rẹ. Bi wọn ṣe pa a tan ni wọn ta le ọkada to gbe wọn wa, ti wọn si sa lọ.

Badejọ ti wọn pa yii ti figba kan ṣiṣẹ ni Space FM ati Naija FM, ti mejeeji wa niluu Ibadan. Bẹẹ lo tun maa n ba wọn kopa ninu sinima agbelewo.

Leave a Reply