Wọn yinbọn pa tọkọ-tiyawo mọle l’Ọta 

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ipohunrere ẹkùn lo n lọ lọwọ bayii ninu ìle bàbá kan, Alagba Kẹ́hìndé Ibidunni ati iyawo ẹ, Elizabeth, tawọn agbebọn wọle wọn laago mẹ́ta oru Ọjọ́ Ìṣègùn, Tusidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, òṣu kẹrin yii, ti wọn si yinbọn pa wọn mọnu ile wọn l’Ọta.
Ojúlé Kẹẹẹdogun,  Opopona Tẹlla Ojo, l’Atan Ọta, ipinlẹ Ogun,  lawọn tọkọ-taya yii n gbe. Olotẹẹli ni Ọgbẹni Ibidunni, iṣẹ́ to n ṣe niyẹn.
Ṣadeede lawọn agbebọn kan bo ile náa loru ọjọ yii, oju irin ferese ti wọn n pe ni bọgilari (burgler proof) ni wọn gba wọle, bi wọn si ti n ba irin naa fa a ki wọn le raaye wọle ni ọmọbinrin kekere to n gbé pẹlu wọn wọle lọ lati sọ ohun to n ṣẹlẹ fun baba.
Bi ọkunrin olotẹẹli naa ṣe jade si wọn lati mọ ohun to n ṣẹlẹ̀ ninu ile ẹ ni wọn yinbọn lu u láya, lọgangan ọkan rẹ, ẹsẹkẹsẹ lo ṣubú lulẹ to ku sinu agbara ẹ̀jẹ́. Bi wọn ṣe pa Kẹ́hìndé Ibidunni tan ni wọn mu iyawo é, Elizabeth.

Wọn gun un lọbẹ, wọn si tun yinbọn fun un. Bi wọn ṣe ri i pe awọn mejeeji ti ku ni wọn sa lọ.

Ọmọ awọn olóogbe yii to n jẹ Ọlayinka, fidi ẹ mulẹ pe awọn kan lo waa pa awọn obi oun.

 O ni wọn da gbogbogbo inu ile ru pelu, wọn si ko iwọnba owo ti wọ́n ba ninu ile naa lọ.
Awọn oku mejeeji ti wa ni mọṣuari bi omọ wọn ti wi. Bi nnkan kan ko ba si yípadà ninu eto alakalẹ fun isinku, ọmọ naa sọ pe ọjọ Ẹti, Furaidee yii, lawọn yoo sinku awọn obi oun.

Leave a Reply