Wọn yinbọn paayan, wọn dana sun agọ ọlọpaa ati mọto Osemawe l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọpọ ẹmi lo ṣofo, tawọn eeyan mi-in si tun fara pa nibi iwọde SARS to n lọ lọwọ niluu Ondo ati Akurẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ta a wa yii.

Ondo to jẹ ibujokoo Iwọ-Oorun ijọba ibilẹ Ondo ni rogbodiyan ọhun ti kọkọ bẹrẹ wẹrẹ.

Ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ Isẹgun, Tusidee, ni Gomina Rotimi Akeredolu deede kede konilegbele oniwakati mẹrinlelogun, to si fi dandan le e pe aago mejila oru ku isẹju kan ni ofin naa gbọdọ bẹrẹ.

Gomina ọhun ni oun pinnu lati tete kede ofin naa lati dena rogbodiyan to n waye lawọn ipinlẹ bii Eko, Ọyọ ati Ọsun nipinlẹ Ondo ni.

Bi ilẹ ọjọ keji, ìyẹn Ọjọruu, Wẹsidee, ṣe mọ lawọn eeyan ti bẹrẹ si i jade si igboro lai ka ofin konilegbele tijọba kede rẹ si, gbogbo ọna to ṣe koko lawọn olufẹhonu han naa di pa, ti wọn si n sun taya lawọn agbegbe bii Ọka, Odojọmu, Ademulẹgun,Yaba atawọn ibòmíràn.

Wahala bẹrẹ l’Ondo lẹyin ti ọlọpaa kan yinbọn lu ọkan ninu awọn olufẹhonu naa lagbegbe Idisin.

Bo ṣe yinbọn ọhun tan ni wọn lo sa wọ inu ọgba banki FCMB to wa nitosi ibi iṣẹlẹ naa, nigba tawọn ọdọ n le e, airi ọlọpaa yii mu lo ṣokunfa bi wọn ṣe fi ibinu dana sun ọkọ meji to jẹ ti banki ọhun, ti wọn si tun ba gbogbo ẹrọ ipọwo wọn jẹ.

Lẹyin eyi ni wọn mori le olu ileesẹ ọlọpaa to wa ni Omimọdẹ, Yaba, niluu Ondo, ti wọn si sa gbogbo ipa to wa ni ikawọ wọn lati dana sun un.

Fun bii wakati marun-un gbako lawọn ọdọ ọhun atawọn ọlọpaa fi doju ija kọ ara wọn, ti iro ibọn si n dun lakọlakọ ni gbogbo asiko naa.

Awọn bii marun-un ni ìbọn ọlọpaa ba, ti wọn si sare gbe wọn lọ sileewosan.

A gbọ pe diẹ ninu awọn ti ìbọn ba ọhun ti ku, ṣugbọn ti a ko ti i le sọ iye wọn ni pato.

Nnkan bii aago mejila ọsan ni Oṣemawe tilu Ondo, Ọba Victor Kiladejọ, gbe awọn ijoye rẹ kan dide lati waa pẹtu sawọn oluwọde naa ninu, ṣugbọn ti gbogbo akitiyan wọn ko so eṣo rere.

Eyi ni wọn si n fa mọ ara wọn lọwọ nigba ti ọgọọrọ awọn obinrin de, ti wọn si mu ọna ọdọ awọn ọlọpaa to duro si ayika teṣan Omimọdẹ pọn.

Bi awọn ọdọ to n binu tẹlẹ ṣe ri wọn ni eegun ija wọn tun le si i, kia ni wọn ti dara pọ mọ wọn, ti gbogbo wọn si jọ n gbiyanju ati wọ inu tesan yii lọ ki awọn awọn ọlọpaa too ṣina ibọn bolẹ.

Kiakia lariwo ti sọ, ti wọn si lawọn ọlọpaa ti mu meji ninu awọn obinrin to n fẹhonu han naa balẹ, bo tilẹ pe ohun ta a pada gbọ ni pe ọkan ninu awọn ọdọ to fẹẹ saaju wọn wọ tesan ni ibọn ba.

Ohun to bi awọn ọdọ naa ninu ree ti wọn fi fabọ le ori ọkọ Oṣemawe to gbe awọn oloye kan wa síbẹ, ti wọn si dana sun un.

Olu ile ẹgbẹ APC to wa lagbegbe Oyemẹkun ni wọn kọkọ fọwọ ba laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee ọhun, alẹ patapata ni wọn tun pada lọ, ti wọn si lọọ dana sun ile ẹgbẹ naa ati ti ẹgbẹ oṣelu PDP to wa lagbegbe Alagbaka.

Nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ni wọn ya bo olu ileesẹ awọn ọlọpaa SARS to wa loju ọna Ọda l’Akurẹ, ko ṣeni to mọ ohun tawọn to n ṣe iwọde ọhun ri ti wọn fi bọ ara wọn sihooho ọmọluabi lasiko ti wọn sun ọfiisi awọn SARS naa nina, gbogbo ọkọ ti wọn ba ninu ọgba wọn ni wọn tun dana sun.

Akitiyan ti wọn lawọn tinu n bi ọhun n ṣe lasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ lọwọ ni bi wọn ṣe fẹẹ raaye wọ inu ọgba ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ondo, ki wọn si tun dana sun un.

Leave a Reply