Yahaya Bello jawe olubori nile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun

Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello, ti jawe olubori nile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun latari ẹjọ tawọn kan pe tako bo ṣe di gomina lẹyin ibo ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ọdun to kọja.

Ninu idajọ ti igbimọ ẹlẹni-marun-un kootu to fikalẹ siluu Abuja ọhun gbe kalẹ, wọn ni awọn ẹjọ mẹrin ti wọn pe tako gomina naa ko lẹsẹ nilẹ.

Igbimọ ti Onidaajọ Adamu Jauro ṣaaju naa fagi le ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu Poeple’s Democratic Party, Actions People’s Party, Social Democratic Party ati Democratic People’s Party pe.

Ṣaaju ni igbimọ to n gbọ ẹjọ to suyọ lasiko ibo ti da ẹjọ onibeji, ninu eyi tawọn adajọ meji ti ni Bello jawe olubori, ti adajọ kẹta si tako ipinnu naa.

Ni bayii, ile-ẹjọ to ga ju nilẹ yii nikan lo ku fun awọn ti idajọ naa ko ba tẹ lọrun.

Ọdun 2015 ni Yahaya Bello di gomina Kogi, o si wọle fun saa keji lọdun to kọja.

Leave a Reply