‘Yahya Bello lo le gbe Naijiria dide, yoo fagba han Tinubu ati Ọṣinbajo’

Monisọla Saka

Awọn alatilẹyin ati olupolongo ibo fun Gomina ipinlẹ Kogi to fẹẹ dupo aarẹ Naijiria lọdun to n bọ, Yahya Bello, fi awọn eeyan ilẹ Naijiria lọkan balẹ pe gomina ipinlẹ Kogi ọhun yoo ṣe bẹbẹ, yoo si ṣe atunto si gbogbo kudiẹ-kudiẹ orilẹ-ede Naijiria bi wọn ba dibo fun un lọdun 2023.
Adari awọn to n polongo fun un naa, Hafsat Abiọla-Costello, lo sọrọ yii di mimọ lakooko ipade kan ti wọn ṣe pẹlu awọn akọroyin kan l’Abuja.
Abiọla Costello to jẹ ọmọ bibi Oloye MKO Abiọla, ẹni ti wọn lo gbegba oroke ninu ibo ‘June 12’, ọdun 1993, ni Bello yoo gbe awọn to lorukọ ninu ibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC to n bọ ṣanle nirọwọ rọsẹ ni.
O tẹsiwaju pe gẹgẹ bii ti baba oun to ti doloogbe, gomina yii ko ni i ba buruburu sabẹ awọn baba isalẹ ninu ijọba rẹ to ba wọle.
Nigba to n dahun ibeere lori boya Bello yoo jawe olubori ninu ibo abẹle, nibi tawọn alagbara, to si tun lorukọ bii Aṣiwaju Bọla Tinubu, Igbakeji Aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo, ati awọn eeyan jankan-jankan miiran wa, Abiọla da wọn lohun pe ‘‘O dara ti ẹ pe wọn ni eeyan jankan-jankan, ṣugbọn lọna irọwọrọsẹ ti ko ni i mu wahala dani ni Bello yoo fi da gbogbo wọn mọlẹ.’’
Abiọla ṣalaye pe Bello ni ibo rẹ yoo tẹwọn ju, nitori ọrọ nipa awọn oludibo lo wa nilẹ yii, niwọn igba ti ida ọgọta awọn ọmọ Naijiria ṣi wa labẹ ọmọ ọgbọn ọdun, awọn ọdọ ilẹ Naijiria si ti n dide si oṣelu ilẹ wọn pẹlu eto ‘Not Too Young To Run’, iyẹn ipolongo to n ta awọn ọdọ ilẹ Naijiria ji lati dide dupo ni orilẹ-ede yii, ti Aarẹ si pada buwọ lu aba ọhun, ohun to daju ṣaka ni pe Yahya Bello to le wa ojutuu si awọn aiṣedeede orilẹ-ede yii ni yoo jawe olu bori ninu ibo abẹle APC ati ti gbogbogboo ni ọdun 2023.

Leave a Reply